ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ẹ̀yin Òbí​—⁠Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọ́n Lè Múnú Jèhófà Dùn

Yorùbá
Ẹ̀yin Òbí​—⁠Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọ́n Lè Múnú Jèhófà Dùn
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202023414/univ/art/202023414_univ_sqr_xl.jpg
mwb23 November ojú ìwé 9

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀yin Òbí​—⁠Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọ́n Lè Múnú Jèhófà Dùn

Ẹ̀yin Òbí​—⁠Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọ́n Lè Múnú Jèhófà Dùn

Àwọn ọmọdé ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. Ó ń kíyè sí bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn. (1Sa 2:26; Lk 2:52) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì kéré, wọ́n lè múnú Jèhófà dùn tí wọ́n bá ń hùwà tó dáa. (Owe 27:11) Jèhófà ti lo ètò rẹ̀ láti pèsè onírúurú nǹkan táwọn òbí lè lò láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì máa ṣègbọràn sí i.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ̀YIN Ọ̀DỌ́—ÌFARADÀ YÍN Ń MÚNÚ JÈHÓFÀ DÙN! KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti pèsè láwọn ọdún tó ti kọjá láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́, kó sì tọ́ wọn sọ́nà?

  • Àwọn nǹkan wo làwọn òbí lè lò lákòókò yìí láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́?

  • Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, àwọn nǹkan wo ni Jèhófà pèsè tó ti ràn ẹ́ lọ́wọ́? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?