ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

“Gbogbo Ilé Áhábù Ló Máa Ṣègbé”—2Ọb 9:8

Yorùbá
“Gbogbo Ilé Áhábù Ló Máa Ṣègbé”—2Ọb 9:8
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202022425/univ/art/202022425_univ_sqr_xl.jpg
mwb22 November ojú ìwé 7

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Gbogbo Ilé Áhábù Ló Máa Ṣègbé”—2Ọb 9:8

“Gbogbo Ilé Áhábù Ló Máa Ṣègbé”—2Ọb 9:8

ÌJỌBA ILẸ̀ JÚDÀ

Jèhóṣáfátì di ọba

nǹkan bíi 911 Ṣ.S.K.: Jèhórámù (ọmọ Jèhóṣáfátì; ọkọ Ataláyà, ọmọbìnrin Áhábù àti Jésíbẹ́lì) di ọba

nǹkan bíi 906 Ṣ.S.K.: Ahasáyà (ọmọ ọmọ Áhábù àti Jésíbẹ́lì) di ọba

nǹkan bíi 905 Ṣ.S.K.: Ataláyà pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ó sì sọ ara ẹ̀ di ọba. Àmọ́, Jèhóádà Àlùfáà Àgbà gbé Jèhóáṣì ọmọ ọmọ rẹ̀ pa mọ́​—2Ọb 11:1-3

898 Ṣ.S.K.: Jèhóáṣì di ọba. Jèhóádà Àlùfáà Àgbà pa Ataláyà.​—2Ọb 11:4-16

ÌJỌBA ILẸ̀ ÍSÍRẸ́LÌ

nǹkan bíi 920 Ṣ.S.K.: Ahasáyà (ọmọ Áhábù àti Jésíbẹ́lì) di ọba

nǹkan bíi 917 Ṣ.S.K.: Jèhórámù (ọmọ Áhábù àti Jésíbẹ́lì) di ọba

nǹkan bíi 905 Ṣ.S.K.: Jéhù pa Ọba Jèhórámù ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtàwọn arákùnrin ẹ̀, ó tún pa ìyá Jèhórámù (ìyẹn Jésíbẹ́lì) àti Ọba Ahasáyà ti ilẹ̀ Júdà àtàwọn arákùnrin ẹ̀.​—2Ọb 9:14–10:17

nǹkan bíi 904 Ṣ.S.K.: Jéhù di ọba