ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Báwo Làwọn Arábìnrin Ṣe Lè Ṣe Púpọ̀ Sí I Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà?

Yorùbá
Báwo Làwọn Arábìnrin Ṣe Lè Ṣe Púpọ̀ Sí I Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà?
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202021414/univ/art/202021414_univ_sqr_xl.jpg
mwb21 November ojú ìwé 9

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Báwo Làwọn Arábìnrin Ṣe Lè Ṣe Púpọ̀ Sí I Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà?

Báwo Làwọn Arábìnrin Ṣe Lè Ṣe Púpọ̀ Sí I Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà?

Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn arábìnrin wa ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Sm 68:11) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ló ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀ jù, àwọn ló pọ̀ jù lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì ń ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, míṣọ́nnárì, iṣẹ́ ìkọ́lé àti iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn arábìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni tẹ̀mí máa ń gbé ìdílé wọn ró, wọ́n sì ń fún ìjọ lókun. (Owe 14:1) Òótọ́ ni pé àwọn arábìnrin ò láǹfààní láti di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n lè ṣe láti ran ìjọ lọ́wọ́. Tó o bá jẹ́ arábìnrin, báwo lo ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

  • Gbìyànjú láti ní àwọn ànímọ́ Kristẹni.​—1Ti 3:11; 1Pe 3:3-6

  • Máa ṣèrànwọ́ fáwọn arábìnrin tí ò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí.​—Tit 2:3-5

  • Máa lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kó o sì mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i

  • Kọ́ èdè míì

  • Lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i

  • Sapá láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí láti yọ̀nda ara rẹ níbi tá a ti ń kọ́ àwọn ilé tá à ń lò fún ìjọsìn

  • Sapá kó o lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN OBÌNRIN TÓ Ń ṢIṢẸ́ KÁRA NÍNÚ OLÚWA,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí lo rí kọ́ látinú ohun táwọn arábìnrin yìí sọ?