ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti Ọ̀sẹ̀ November 15-21, 2021

Yorùbá
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti Ọ̀sẹ̀ November 15-21, 2021
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202021406/univ/art/202021406_univ_sqr_xl.jpg
mwb21 November ojú ìwé 5

November 15-21

JÓṢÚÀ 23-24

November 15-21
  • Orin 50 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 28

  • Yẹra fún Ẹgbẹ́ Búburú Níbi Iṣẹ́: (7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ káwọn ará wo fídíò Yẹra fún Ohun Tó Lè Ba Ìdúróṣinṣin Rẹ Jẹ́​—Ẹgbẹ́ Búburú. Lẹ́yìn náà béèrè pé: Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Kẹ́mi nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́ níbiiṣẹ́? Àyípadà wo ni Arábìnrin Kẹ́mi ṣe, báwo nìyẹn sì ṣe ràn án lọ́wọ́? Kí lo rí kọ́ nínú fídíò yìí nípa bó o ṣe lè yẹra fún ẹgbẹ́ búburú?

  • Wá Àwọn Ọ̀rẹ́ Ní Ibi Tí O Ò Lérò: (8 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ káwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé: Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Akil tó mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́ rìn níléèwé? Báwo ló ṣe rí ọ̀rẹ́ gidi nínú ìjọ? Kí lo rí kọ́ nínú fídíò yìí tá ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ọ̀rẹ́ gidi?

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 16 ¶1-8 àti fídíò ohun tó wà ní orí 16

  • Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)

  • Orin 39 àti Àdúrà