ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ẹyọ Owó Kéékèèké Méjì’ Tó Níye Lórí

Yorùbá
‘Ẹyọ Owó Kéékèèké Méjì’ Tó Níye Lórí
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202020406/univ/art/202020406_univ_sqr_xl.jpg
mwb20 November ojú ìwé 8

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹyọ Owó Kéékèèké Méjì’ Tó Níye Lórí

Ẹyọ Owó Kéékèèké Méjì’ Tó Níye Lórí

Owó tí opó yìí fi ṣètọrẹ ò tó láti ra oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. (Wo “gbogbo ohun tó ní láti gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lúùkù 21:4, nwtsty.) Àmọ́ ohun tó ṣe yìí fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì mọyì ìjọsìn rẹ̀. Ìyẹn ló mú kí ohun tó fi ṣètọrẹ ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà.​—Mk 12:43.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ‘WỌ́N MÚ Ẹ̀BÙN WÁ FÚN JÈHÓFÀ’, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí la máa ń fi owó tá a fi ń ṣètọrẹ ṣe?

  • Kí nìdí táwọn ọrẹ wa fi ṣeyebíye tó bá tiẹ̀ dà bíi pé kò tó nǹkan?

  • Ibo la ti lè rí ìsọfúnni nípa àwọn ọ̀nà míì tẹ́ ẹ lè gbà ṣètọrẹ lágbègbè yín?​—Wo àpótí náà “ Mọ Púpọ̀ Sí I Lórí Ìkànnì