ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Àǹfààní Tí Àtẹ Tó Ṣeé Tì Kiri Ti Ṣe Wá Kárí Ayé

Yorùbá
Àǹfààní Tí Àtẹ Tó Ṣeé Tì Kiri Ti Ṣe Wá Kárí Ayé
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202018410/univ/art/202018410_univ_sqr_xl.jpg

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àǹfààní Tí Àtẹ Tó Ṣeé Tì Kiri Ti Ṣe Wá Kárí Ayé

Àǹfààní Tí Àtẹ Tó Ṣeé Tì Kiri Ti Ṣe Wá Kárí Ayé

Ìṣe orí karùn-ún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lọ sínú tẹ́ńpìlì, níbi tí ọ̀pọ̀ èèyàn wà, kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere fún wọn. (Iṣe 5:​19-21, 42) Lónìí, àtẹ tó ṣeé tì kiri tá à ń lò láwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn wà ti so èso rere.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀǸFÀÀNÍ TÍ ÀTẸ TÓ ṢEÉ TÌ KIRI TI ṢE WÁ KÁRÍ AYÉ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Ìgbà wo la bẹ̀rẹ̀ sí í fi àtẹ tó ṣeé tì kiri wàásù, báwo ló sì ṣe bẹ̀rẹ̀?

  • Àwọn ọ̀nà wo ni àtẹ tó ṣeé tì kiri gbà dáa ju tábìlì tá a fi ń pàtẹ ìwé?

  • Kí la rí kọ́ látinú ìrírí Mi Jung You?

  • Báwo ni ìrírí Arákùnrin Jacob Salomé ṣe jẹ́ ká rí i pé àtẹ tó ṣeé tì kiri dára gan-an?

  • Kí ni ìrírí Annies àti ọkọ rẹ̀ kọ́ wa nípa bá a ṣe lè fi àtẹ tó ṣeé tì kiri wàásù lọ́nà tó gbéṣẹ́?