ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti June 22-28, 2026

Yorùbá
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti June 22-28, 2026
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202026168/univ/art/202026168_univ_sqr_xl.jpg
mwb26 May ojú ìwé 14

June 22-28

JEREMÁYÀ 9-10

June 22-28

Orin 5 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Kí Lo Máa Ń Fi Yangàn?

(10 min.)

Má ṣe máa fọ́nnu nípa àwọn ẹ̀bùn tó o ní àtàwọn àṣeyọrí ẹ, káwọn èèyàn lè máa gbé ẹ gẹ̀gẹ̀ (Jer 9:23; w20.07 6 ¶13-15)

Tó o bá ń wá ọ̀nà láti sọ̀rọ̀ tó dáa nípa Jèhófà, ò ń fi orúkọ Jèhófà yangàn nìyẹn (Jer 9:24; w25.05 30 ¶14)

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀ (1Kọ 2:1-5; w25.09 23-24 ¶12)

Àwọn nǹkan tá a fi ń yangàn lè ṣe àwọn míì láǹfààní, ó sì lè ṣàkóbá fún wọn

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Jer 10:21—Kí làwọn alábòójútó nínú ètò Ọlọ́run lè kọ́ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? (jr 133-134 ¶11-12)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 5)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)

6. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 3)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 48

7. Máa Ronú Nípa Ìjọba Ọlọ́run, Má Ṣe Jẹ́ Kí Wọ́n Tàn Ẹ́ Jẹ (Jer 10:23)

(15 min.) Ìjíròrò.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé,

  • Àwọn nǹkan wo ló lè mú ká má fọkàn sí Ìjọba Ọlọ́run mọ́?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 58 àti Àdúrà