ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti May 12-18, 2025

Yorùbá
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti May 12-18, 2025
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202025162/univ/art/202025162_univ_sqr_xl.jpg
mwb25 May ojú ìwé 4-5

May 12-18

ÒWE 13

May 12-18

Orin 34 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Má Ṣe Jẹ́ Kí “Fìtílà Àwọn Ẹni Burúkú” Tàn Ẹ́ Jẹ

(10 min.)

Àwọn èèyàn burúkú ò nírètí ọjọ́ iwájú (Owe 13:9; it-2 196 ¶2-3)

Yẹra fún àwọn tó ń fi nǹkan búburú ṣayọ̀ (Owe 13:20; w12 7/15 12 ¶3)

Jèhófà máa ń bù kún àwọn olódodo (Owe 13:25; w04 7/15 31 ¶6)

Ó máa ń dà bíi pé àwọn tó ń lépa àwọn nǹkan ayé yìí ń gbádùn ara wọn, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Àwọn tó ń sin Jèhófà ló máa ń ní ayọ̀ tòótọ́

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Owe 13:24—Ìkìlọ̀ wo ni Bíbélì yìí fún wa tó bá dọ̀rọ̀ bíbá ọmọ wí? (it-2 276 ¶2)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ohun kan tó ṣẹlẹ̀ ládùúgbò yín bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ, lẹ́yìn náà fi ohun kan hàn án nínú Bíbélì tó máa nífẹ̀ẹ́ sí. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Pe ẹni náà wá sípàdé. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 3)

6. Àsọyé

(5 min.) lmd àfikún A kókó 9—Àkòrí: Táwọn Ọmọ Bá Ń Bọ̀wọ̀ Fáwọn Òbí Wọn Tí Wọ́n sì Jẹ́ Onígbọràn, Nǹkan Á Máa Lọ Dáadáa fún Wọn. (th ẹ̀kọ́ 16)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 77

7. “Ìmọ́lẹ̀ Àwọn Olódodo Mọ́lẹ̀ Rekete”

(8 min.) Ìjíròrò.

Ìmọ̀ àti ọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò láfiwé. Tá a bá ń fi ohun tá a kọ́ nínú ẹ̀ sílò, a máa ní ayọ̀ tòótọ́, ìgbésí ayé wa sì máa nítumọ̀. Ayé Sátánì ò lè fún wa láwọn nǹkan yìí láé.

Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Ayé Yìí Ò Lè Fún Ẹ Ní Ohun Tí Kò Ní. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Báwo ni ìrírí Arábìnrin Gainanshina ṣe jẹ́ ká rí i pé “ìmọ́lẹ̀ àwọn olódodo” dáa ju “fìtílà àwọn ẹni burúkú” lọ?—Owe 13:9

Má ṣe máa ronú nípa àwọn nǹkan tó wà nínú ayé tàbí kó o máa kábàámọ̀ àwọn ìpinnu tó o ṣe tó jẹ́ kó o lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (1Jo 2:15-17) Kàkà bẹ́ẹ̀, ‘ìmọ̀ tó ṣeyebíye ju ohun gbogbo lọ’ tó o ní ni kó o gbájú mọ́.—Flp 3:8.

8. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ

(7 min.)

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 26 ¶9-17

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 43 àti Àdúrà