ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti May 27–June 2, 2024

Yorùbá
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti May 27–June 2, 2024
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202024164/univ/art/202024164_univ_sqr_xl.jpg
mwb24 May ojú ìwé 6-7

May 27–June 2

SÁÀMÙ 42-44

May 27–June 2

Orin 86 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Máa Fi Ohun Tí Jèhófà Ń Kọ́ Wa Sílò

(10 min.)

Máa jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará lójúkojú tó bá ti lè ṣeé ṣe tó (Sm 42:4, 5; w06 6/1 9 ¶4)

Kọ́kọ́ gbàdúrà kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (Sm 42:8; w12 1/15 15 ¶2)

Máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe (Sm 43:3)

Ohun tí Jèhófà ń kọ́ wa máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa, ká sì dúró lórí ìpinnu tá a ṣe nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà.—1Pe 5:10; w16.09 5 ¶11-12.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 44:19—Kí ló ṣeé ṣe kí onísáàmù náà ní lọ́kàn nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “níbi tí àwọn ajáko ń gbé”? (it-1 1242)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(5 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Pe ẹni náà wá sí àsọyé fún gbogbo èèyàn tẹ́ ẹ máa gbọ́ lọ́sẹ̀ yẹn. Fi fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? hàn án, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀ (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 5)

6. Àsọyé

(3 min.) lmd àfikún A kókó 4—Àkòrí: Ara Gbogbo Èèyàn Máa Jí Pépé. (th ẹ̀kọ́ 2)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 21

7. Bó O Ṣe Lè Ṣèpinnu Tó Dáa Tó Bá Dọ̀rọ̀ Iṣẹ́ àti Ilé Ẹ̀kọ́

(15 min.) Ìjíròrò.

Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ṣé ẹ ti ń ronú ohun tẹ́ ẹ máa ṣe tẹ́ ẹ bá parí ilé ìwé? Ó ṣeé ṣe kó o ti ní iṣẹ́ kan lọ́kàn tó máa jẹ́ kó o lè ráyè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ó sì ṣeé ṣe kó o ti máa ronú irú iṣẹ́ tó wù ẹ́ láti kọ́, tàbí àfikún ẹ̀kọ́ tó o lè gbà tí wọ́n á sì fún ẹ ní ìwé ẹ̀rí tó o fi máa rí irú iṣẹ́ tó wù ẹ́ láti ṣe. Ká sòótọ́, inú ẹ lè máa dùn bó o ṣe ń fojú sọ́nà fún àkókò yẹn. Àmọ́ nígbà míì, kì í rọrùn láti ṣèpinnu, àwọn èèyàn sì lè máa rọ̀ ẹ́ lọ́tùn-ún lósì pé kó o yan ohun tí wọ́n ronú pé ó dáa jù fún ẹ. Kí lá jẹ́ kó o ṣèpinnu tó dáa?

Ka Mátíù 6:32, 33. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o kọ́kọ́ pinnu ohun tó o fẹ́ ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kó o tó yan irú iṣẹ́ tó o máa ṣe tàbí tó o máa kọ́?

  • Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti fi ìmọ̀ràn inú Mátíù 6:32, 33 sílò?—Sm 78:4-7

Ṣọ́ra kó má lọ jẹ́ torí àti ríṣẹ́ táá máa mówó ńlá wọlé tàbí torí àtidi gbajúmọ̀ lo fi máa pinnu ohun tó o fẹ́ ṣe. (1Jo 2:15, 17) Má gbàgbé pé, téèyàn bá lówó rẹpẹtẹ, ìyẹn lè mú kó ṣòro fún un láti fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. (Lk 18:24-27) Tẹ́nì kan bá ń lé bó ṣe máa di olówó, á ṣòro fún un láti pọkàn pọ̀ sórí ìjọsìn Jèhófà, kó sì tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—Mt 6:24; Mk 8:36.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Má Ṣe Gbọ́kàn Lé Àwọn Nǹkan Tó Máa Dópin!—Ọrọ̀. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  •   Kí ni Òwe 23:4, 5 sọ táá jẹ́ kó o lè ṣèpinnu tó dáa?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 10 ¶5-12

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 47 àti Àdúrà