ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

“Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Jèhófà Ọlọ́run Yín”

Yorùbá
“Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Jèhófà Ọlọ́run Yín”
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202023165/univ/art/202023165_univ_sqr_xl.jpg
mwb23 May ojú ìwé 4

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Jèhófà Ọlọ́run Yín”

“Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Jèhófà Ọlọ́run Yín”

Nígbà táwọn ọ̀tá ń halẹ̀, Jèhóṣáfátì àtàwọn èèyàn Júdà bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́ (2Kr 20:12, 13; w14 12/15 23 ¶8)

Jèhófà fi àwọn èèyàn náà lọ́kàn balẹ̀, ó sì fún wọn ní ìtọ́ni tó ṣe kedere (2Kr 20:17)

Jèhófà gba àwọn èèyàn ẹ̀ sílẹ̀ torí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e (2Kr 20:21, 22, 27; w21.11 16 ¶7)

Tí Gọ́ọ̀gù bá gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà nígbà ìpọ́njú ńlá, àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìtọ́ni àwọn tó yàn láti máa ṣàbójútó kò ní bẹ̀rù ohunkóhun.​—2Kr 20:20.