Yorùbá
Bí Àwọn Ará Wa Ní Caribbean Ṣe Jàǹfààní Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìrànwọ́ Tá À Ń Ṣe
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202019166/univ/art/202019166_univ_sqr_xl.jpg

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bí Àwọn Ará Wa Ní Caribbean Ṣe Jàǹfààní Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìrànwọ́ Tá À Ń Ṣe

Bí Àwọn Ará Wa Ní Caribbean Ṣe Jàǹfààní Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìrànwọ́ Tá À Ń Ṣe

Bíi tàwọn ará ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwa náà ní àǹfààní láti fi hàn pé a fẹ́ràn àwọn ará wa tí àjálù dé bá. (Jo 13:34, 35) Láti rí bí àwọn ará ṣe ṣèrànwọ́ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn ní Caribbean nígbà tí àjálù dé bá wọn, wo fídíò náà Ìfẹ́ Sún Wọn Ṣiṣẹ́​—Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù Tó Wáyé Láwọn Erékùṣù Caribbean, lẹ́yìn náà dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa ní Caribbean nígbà tí ìjì líle Hurricane Irma àti Hurricane Maria ṣọṣẹ́?

  • Báwo ni Jèhófà ṣe lo àwọn ará láti ṣèrànwọ́ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn ní Caribbean?

  • Báwo ló ṣe rí lára àwọn ará tí àjálù dé bá nígbà tí àwọn ará fi ìfẹ́ hàn sí wọn?

  • Àwọn arákùnrin àti arábìnrin mélòó ló ti lọ́wọ́ nínú ètò ìrànwọ́ yìí ní Caribbean?

  • Kí ni gbogbo wa lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará tí àjálù dé bá?

  • Nígbà tó o wo fídíò yìí, báwo ló ṣe rí lára rẹ pé o wà nínú ètò tó ń fi ìfẹ́ hàn?