ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁÀKÙ 13-14
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Èèyàn Dẹkùn Mú Ẹ
Kí nìdí tí àwọn àpọ́sítélì fi jẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn mú wọn?
Wọ́n dá ara wọn lójú jù. Pétérù tiẹ̀ tún ronú pé òun máa dúró ti Jésù ju àwọn àpọ́sítélì tó kù lọ
Wọn ò wà lójúfò, wọn ò sì gbàdúrà
Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, kí ló ran àwọn àpọ́sítélì tó ti ronú pìwà dà yìí lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn dẹkùn mú wọn, tí wọ́n sì ń wàásù láìka àtakò sí?
Wọ́n fi ìkìlọ̀ Jésù sọ́kàn, torí náà wọ́n ti wà ní ìmúrasílẹ̀ fún àtakò tàbí inúnibíni
Wọ́n gbára lé Jèhófà, wọ́n sì ń gbàdúrà.—Iṣe 4:24, 29
Irú ipò wo ló lè dán ìgboyà wa wò?