ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti March 23-29, 2026

Yorùbá
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti March 23-29, 2026
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202026084/univ/art/202026084_univ_sqr_xl.jpg
mwb26 March ojú ìwé 6-7

March 23-29

ÀÌSÁYÀ 48-49

March 23-29

Orin 89 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Tó O Bá Fetí sí Jèhófà, Ó Máa Ṣe Ẹ́ Láǹfààní

(10 min.)

Jèhófà ń kọ́ àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ (Ais 48:17; it “Olùkọ́, Kíkọ́ni” ¶2)

A gbọ́dọ̀ pinnu pé Jèhófà la máa fetí sí (Ais 48:18a; ijwbq àpilẹ̀kọ 44 ¶2-3)

Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àlàáfíà wa máa “dà bí odò,” òdodo wa sì máa “dà bí ìgbì òkun” (Ais 48:18b; lv 199 ¶8)

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “àlàáfíà” lè túmọ̀ sí kéèyàn ní ìlera tó dáa, kí ọkàn ẹ̀ balẹ̀, kí ọpọlọ ẹ̀ pé, kí nǹkan máa lọ dáadáa fún un, kó láwọn ọ̀rẹ́ gidi, kó sì ní gbogbo nǹkan.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Ais 48:17—Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń dáhùn nípàdé? (w19.01 9-10 ¶7)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Pe mọ̀lẹ́bí ẹ kan tí kò wá sípàdé mọ́ sí àkànṣe àsọyé àti Ìrántí Ikú Kristi. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 3)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Sọ àwọn nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ níbi Ìrántí Ikú Kristi fún ẹnì kan tó sọ pé ó ṣeé ṣe kóun wá. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)

6. Pa Dà Lọ

(5 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Lẹ́yìn tá a parí Ìrántí Ikú Kristi, ẹni náà béèrè àwọn nǹkan kan nípa ohun tó gbọ́ níbẹ̀. Dáhùn àwọn ìbéèrè ẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 107

7. Bá A Ṣe Lè Fi Hàn Pé A Mọyì Ọjọ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ́dún

(15 min.) Ìjíròrò.

Bá a ṣe ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún, ṣe là ń pa àṣẹ Jésù mọ́, tá a sì ń fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn ìràpadà tí Jèhófà fún wa. (Lk 22:19) Bákan náà, Ìrántí Ikú Kristi máa ń jẹ́ ká rántí bí Jèhófà àti Jésù Ọmọ ẹ̀ ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. (Ga 2:20; 1Jo 4:9, 10) Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi, ká sì fi hàn pé a mọyì ìràpadà tí Jèhófà pèsè fún wa? Báwo la ṣe lè ran àwọn tá a pè wá síbẹ̀ lọ́wọ́ káwọn náà lè jàǹfààní?

  • Má jẹ́ kí ọjọ́ kan lọ láìka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a ṣètò fún Ìrántí Ikú Kristi

  • Máa ronú lórí ẹ̀bùn ìràpadà àti bó o ṣe lè máa gbé ìgbésí ayé ẹ lọ́nà tó fi hàn pé o mọyì ẹ̀

  • Rí i pé o pe àwọn tó o mọ̀, àwọn mọ̀lébí àtàwọn ará àdúgbò ẹ wá síbi àkànṣe àsọyé àti Ìrántí Ikú Kristi

  • Tó o bá rí àwọn tá a pè wá, rẹ́rìn-ín sí wọn, kó o sì fi ọ̀yàyà kí wọn káàbọ̀. Òótọ́ ni pé àwọn tó o pè wá lo máa fún ní àfiyèsí jù, àmọ́ ó tún yẹ kó o kíyè sí àwọn tó wá torí wọ́n rí ìwé ìkésíni gbà. O lè ní kí wọ́n wá jókòó tì ẹ́

  • Wáyè dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá bi ẹ́

  • Rí i pé o kí àwọn tó ti pẹ́ tí wọ́n ti wá sípàdé káàbọ̀. Ó yẹ kẹ́yin alàgbà dìídì kíyè sí àwọn tá a ti mú kúrò nínú ìjọ tó bá wá lọ́jọ́ yẹn, kẹ́ ẹ sì kí wọn káàbọ̀

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Jésù “Wá Láti Wá Kiri àti Láti Gba Ohun Tí Ó Sọnù Là.” Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí lo kọ́ nípa ìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa fi ọ̀yàyà kí àwọn tí kò wá sípàdé mọ́ tí wọ́n bá wá síbi Ìrántí Ikú Kristi?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 134 àti Àdúrà