March 2-8
ÀÌSÁYÀ 41-42
Orin 8 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. “Má Bẹ̀rù”
(10 min.)
Jèhófà máa gbé “ẹnì kan dìde láti ibi tí oòrùn ti ń yọ” tó máa mú kí àwọn èèyàn wárìrì (Ais 41:2, 5; ip-2 20 ¶10)
Kò sídìí fáwọn èèyàn Jèhófà nígbà yẹn láti bẹ̀rù (Ais 41:10; ijwbv àpilẹ̀kọ 5 ¶4-7)
Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ (Ais 41:13)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Àìsáyà orí 41 ṣe lè ran àwa Kristẹni lọ́wọ́ lónìí?—w16.07 18 ¶4-5.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Ais 41:8—Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé ọ̀rẹ́ òun ni Ábúráhámù lóòótọ́? (w01 10/1 20 ¶3)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Ais 42:1-13 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. O fún ẹnì kan níwèé tá a fi ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi, ẹni náà sì sọ pé ó wu òun láti wá. (lmd ẹ̀kọ́ 6 kókó 4)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Pe ọ̀kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ wá sí Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì bá a wá Ilé Ìpàdé tó sún mọ́ ọn lórí jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 5)
6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(5 min.) Àsọyé. ijwbq àpilẹ̀kọ 60—Àkòrí: Báwo Lo Ṣe Lè Borí Ìbẹ̀rù Ikú? (th ẹ̀kọ́ 1)
Orin 19
7. A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pe Àwọn Èèyàn sí Ìrántí Ikú Kristi ní Saturday, March 7
(5 min.) Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó sọ àsọyé yìí. Sọ ètò tí ìjọ ṣe láti pe àwọn èèyàn wá sí àkànṣe àsọyé àti Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì sọ àwọn ètò míì tó wà nílẹ̀. Gba àwọn ará níyànjú láti fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lóṣù March àti April. Àwọn akéde tó bá ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láwọn oṣù yìí lè ròyìn wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15).
8. Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe ti Oṣù March
(10 min.) Ìjíròrò.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Lẹ́yìn náà béèrè àwọn ìbéèrè tó wà nínú fídíò náà.
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 66-67

