April 27–May 3
ÀÌSÁYÀ 56-57
Orin 12 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Inú Wa Dùn Pé Jèhófà Ni Ọlọ́run Wa
(10 min.)
Àwọn òrìṣà ò lè gba àwọn tó ń jọ́sìn wọn sílẹ̀ (Ais 57:13; ip-2 269 ¶14-16)
Àwọn tí ò sin Jèhófà ò lè ní ìsinmi, ọkàn wọn ò sì lè balẹ̀ (Ais 57:20; w18.06 7 ¶16)
Kò sí àlàáfíà fún ẹni burúkú (Ais 57:21; it “Àlàáfíà” ¶3)
BI ARA RẸ PÉ, Tí mo bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ káyé mi dáa sí i?
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Ais 56:6, 7—Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń ṣẹ lónìí? (w07 1/15 10 ¶3; w06 11/1 27 ¶1)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Ais 56:4-12 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Sọ ohun tó o kọ́ nípàdé láìpẹ́ yìí fún ẹnì kan. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)
5. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(5 min.) Àsọyé. ijwbq àpilẹ̀kọ 90—Àkòrí: Ṣé Ó Pọn Dandan Kéèyàn Máa Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Kan Pàtó? (th ẹ̀kọ́ 16)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(4 min.) lff ẹ̀kọ́ 19 kókó 4 (lmd ẹ̀kọ́ 11 kókó 3)
Orin 58
7. Má Jẹ́ Kó Sú Ẹ Láti Máa Sọ̀rọ̀ Nípa Jèhófà
(15 min.) Ìjíròrò.
Ayé àwọn tí ò sin Jèhófà kì í nítumọ̀, wọn ò lẹ́ni gidi tó lè tọ́ wọn sọ́nà, wọn ò sì nírètí pé ọ̀la ṣì máa dáa. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú wọn kì í tẹ́tí sí ìhìn rere torí wọn ò mọ̀ pé ìyẹn ló máa tún ayé wọn ṣe. Torí náà, a kì í jẹ́ kó sú wa tàbí ká rẹ̀wẹ̀sì táwọn èèyàn ò bá tẹ́tí sí wa. Àmọ́ kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?—Onw 11:6.
-
Àwọn ẹni tuntun lè kó wá. Àwọn tí ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wa lè kó kúrò ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, káwọn míì tó kó wá sì ṣe tán láti tẹ́tí sí wa
-
Ó lè jẹ́ ẹlòmíì ló máa jáde sí wa tá a bá pa dà lọ síbẹ̀. Ó lè jẹ́ òbí wọn àgbà, ọmọ kan tó ti wá dàgbà báyìí, ẹni tuntun tí wọ́n jọ ń gbé tàbí àlejò kan ló máa wá ṣílẹ̀kùn
-
Àwọn èèyàn máa ń yí pa dà. (1Ti 1:13) Àjálù tó ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan tàbí bí nǹkan ṣe túbọ̀ ń le láyé lè mú kẹ́nì kan bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́rọ̀ wa
-
Bá ò ṣe jẹ́ kó sú wa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.—Lk 6:45; 1Jo 5:3
Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Jèhófà ‘Ò Jìnnà sí Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Wa.’ Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Kí lo kọ́ nínú fídíò yẹn tí ò ní jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù sú ẹ?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 80-81

