ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Má Ṣe Fara Wé Àwọn Aláìdúróṣinṣin

Yorùbá
Má Ṣe Fara Wé Àwọn Aláìdúróṣinṣin
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202021093/univ/art/202021093_univ_sqr_xl.jpg
mwb21 March ojú ìwé 9

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Má Ṣe Fara Wé Àwọn Aláìdúróṣinṣin

Má Ṣe Fara Wé Àwọn Aláìdúróṣinṣin

Kórà, Dátánì àti Ábírámù ò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ètò tí Jèhófà ṣe, ìyẹn sì fi hàn pé wọn kì í ṣe adúróṣinṣin. Jèhófà pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run, títí kan gbogbo àwọn tó tì wọ́n lẹ́yìn. (Nọ 16:​26, 27, 31-33) Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà? Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin?

WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁ ṢE FARA WÉ ÀWỌN ALÁÌDÚRÓṢINṢIN, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Nadia tó dán an wò, àpẹẹrẹ wo ló sì rí nínú Bíbélì tó ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin?

  • Kí ló mú kí arákùnrin kan bínú sí àwọn alàgbà, àpẹẹrẹ wo ló sì rí nínú Bíbélì tó ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin?

  • Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Terrance tó dán an wò, àpẹẹrẹ wo ló sì rí nínú Bíbélì tó ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin?

  • Kí ló ṣẹlẹ̀ nílé ìwé tó dán arákùnrin kan wò, àpẹẹrẹ wo ló sì rí nínú Bíbélì tó ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin?