ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Bí Ìgbàgbọ́ Ṣe Lè Jẹ́ Ká Nígboyà

Yorùbá
Bí Ìgbàgbọ́ Ṣe Lè Jẹ́ Ká Nígboyà
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202021089/univ/art/202021089_univ_sqr_xl.jpg
mwb21 March ojú ìwé 6

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Bí Ìgbàgbọ́ Ṣe Lè Jẹ́ Ká Nígboyà

Bí Ìgbàgbọ́ Ṣe Lè Jẹ́ Ká Nígboyà

Àwọn amí tó mú ìròyìn burúkú wá ò nígbàgbọ́ (Nọ 13:​31-33; 14:11)

Torí pé àwọn amí mẹ́wàá yẹn ò nígbàgbọ́, wọ́n kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn tó kù (Nọ 14:​1-4)

Àwọn amí tó jẹ́ onígboyà fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ tó lágbára (Nọ 14:​6-9; w06 10/1 17 ¶5-6)

Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fojú ara wọn rí bí Jèhófà ṣe gbà wọ́n là, tó sì jà fún wọn. Ó yẹ kí àwọn nǹkan tí wọ́n rí yẹn mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára, kí wọ́n sì gbà pé Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Kénáánì.