Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 24

Bí Ísákì Ṣe Rí Ìyàwó

Bí Ísákì Ṣe Rí Ìyàwó

24:​2-4, 11-15, 58, 67

Ìránṣẹ́ Ábúráhámù bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ láti rí ìyàwó gidi fún Ísákì. (Jẹ 24:​42-44) Ó yẹ káwa náà máa bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà ká tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì nígbèésí ayé wa. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

  • Gbàdúrà

  • Ka ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run sọ kó o tó ṣèpinnu

  • Gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn