ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

“Màá Wà Pẹ̀lú Rẹ Bí O Ṣe Ń Sọ̀rọ̀”

Yorùbá
“Màá Wà Pẹ̀lú Rẹ Bí O Ṣe Ń Sọ̀rọ̀”
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202020212/univ/art/202020212_univ_sqr_xl.jpg
mwb20 June ojú ìwé 7

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 4-5

“Màá Wà Pẹ̀lú Rẹ Bí O Ṣe Ń Sọ̀rọ̀”

“Màá Wà Pẹ̀lú Rẹ Bí O Ṣe Ń Sọ̀rọ̀”

4:10-15

Jèhófà ran Mósè lọ́wọ́ kó lè borí ìbẹ̀rù rẹ̀. Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Jèhófà sọ fún Mósè?

  • Kò yẹ ká máa ronú jù nípa ibi tá a kù sí

  • Ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa ní ohunkóhun tá a bá nílò ká lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ wa

  • Tá a bá nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run, a ò ní bẹ̀rù èèyàn

Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà ràn mí lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tí mo dojú kọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?