ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Àwọn Àgbàlagbà Ní Ohun Púpọ̀ Láti Kọ́ Wa

Yorùbá
Àwọn Àgbàlagbà Ní Ohun Púpọ̀ Láti Kọ́ Wa
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202020207/univ/art/202020207_univ_sqr_xl.jpg
mwb20 June ojú ìwé 4

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 48-50

Àwọn Àgbàlagbà Ní Ohun Púpọ̀ Láti Kọ́ Wa

Àwọn Àgbàlagbà Ní Ohun Púpọ̀ Láti Kọ́ Wa

48:21, 22; 49:1; 50:24, 25

Táwọn àgbàlagbà bá sọ ohun tí wọ́n ti rí nípa àwọn “iṣẹ́ àgbàyanu” tí Jèhófà ń ṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ìyẹn máa ń mú kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀ túbọ̀ lágbára. (Sm 71:17, 18) Tẹ́ ẹ bá láwọn àgbàlagbà nínú ìjọ yín, o lè bi wọ́n nípa

  • bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa sìn ín nìṣó láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n ní sí

  • bó ṣe rí lára wọn bí wọ́n ṣe ń rí i tí àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ń pọ̀ sí i

  • bí inú wọn ṣe ń dùn láti rí bí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ṣe túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i

  • àwọn ìyípadà tó ti wáyé nínú ètò Ọlọ́run