Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Fọgbọ́n Yan Eré Ìnàjú Tí Wàá Máa Ṣe

Fọgbọ́n Yan Eré Ìnàjú Tí Wàá Máa Ṣe

Kí nìdí tó fi yẹ ká fọgbọ́n yan eré ìnàjú tá a máa ṣe? Ìdí ni pé tá a bá yan fíìmù kan tá a fẹ́ wò, orin tá a fẹ́ gbọ́, ìkànnì kan tá a fẹ́ lọ, ìwé kan tá a fẹ́ kà tàbí géèmù tá a fẹ́ gbá, ṣe là ń yan ohun tá a fẹ́ fi kúnnú ọkàn wa. Ohun tá a bá yàn máa nípa lórí ìwà wa. Ó ṣeni láàánú pé púpọ̀ lára àwọn eré ìnàjú tó wà lónìí ló ní àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra nínú. (Sm 11:5; Ga 5:​19-21) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi rọ̀ wá pé ká máa ronú lórí àwọn nǹkan tó máa mú ògo wá fún Jèhófà.​—Flp 4:8.

WO FÍDÍÒ NÁÀ ERÉ ÌNÀJÚ WO LÓ YẸ KÍ N YÀN LÁÀYÒ? KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo ni ìjà àjàkú akátá tí wọ́n ń jà ní Róòmù láyé àtijọ́ ṣe jọra pẹ̀lú àwọn eré ìnàjú kan lóde òní?

  • Báwo ni àwọn ará ìjọ ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti yan eré ìnàjú tó gbámúṣé?

  • Báwo ló ṣe yẹ kí Róòmù 12:9 ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ yan eré ìnàjú?

  • Irú àwọn eré ìnàjú tó gbámúṣé wo ló wà ní àdúgbò rẹ?