ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Kọ Ìdẹwò Bí I Ti Jésù

Yorùbá
Kọ Ìdẹwò Bí I Ti Jésù
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202018211/univ/art/202018211_univ_sqr_xl.jpg

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 4-5

Kọ Ìdẹwò Bí I Ti Jésù

Kọ Ìdẹwò Bí I Ti Jésù

Sátánì máa ń gbìyànjú láti ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ nípa mímú ká máa ro èròkérò. Ó máa ń lo ọgbọ́n yìí fún wa lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ níbàámu pẹ̀lú ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nífẹ̀ẹ́ sí àti ipò tá a wà.

Ohun ìjà tó lágbára wo ni Jésù lò láti fi borí àwọn ìdẹwò mẹ́ta tí Sátánì sábà máa ń lò? (Heb 4:12; 1Jo 2:15, 16) Báwo ni mo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

  • 4:1-4

    “Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara”

  • 4:5-8

    “Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú”

  • 4:9-12

    “Ṣekárími”