Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣàṣeyọrí

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣàṣeyọrí

Ó máa ń wu àwọn òbí tó níbẹ̀rù Ọlọ́run láti rí bí àwọn ọmọ wọn ṣe ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà. Àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti sin Jèhófà tí wọ́n bá gbin ẹ̀kọ́ Bíbélì sínú ọkàn wọn láti kékeré. (Di 6:7; Owe 22:6) Ǹjẹ́ ó gba pé kí àwọn òbí yááfì àwọn nǹkan kan? Bẹ́ẹ̀ ni! Àmọ́ èrè tí wọ́n máa rí tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.​—3Jo 4. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ làwọn òbí lè kọ́ lára Jósẹ́fù àti Màríà. Ó ‘jẹ́ àṣà wọn láti máa lọ sí Jerúsálẹ́mù láti ọdún dé ọdún fún àjọyọ̀ ìrékọjá,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gba ọ̀pọ̀ ìsapá àti ìnáwó. (Lk 2:41) Ó ṣe kedere pé ipò kìíní ni Jósẹ́fù àti Màríà fi àjọṣe ìdílé wọn pẹ̀lú Jèhófà sí. Bákan náà, ó yẹ kí àwọn òbí lóde òní máa lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n bá ní láti darí àwọn ọmọ wọn sí ojú ọ̀nà tó yẹ nípa ọ̀rọ̀ ẹnu àti àpẹẹrẹ wọn.​—Sm 127:​3-5.

WO FÍDÍÒ NÁÀ WỌ́N GBÁ ÀǸFÀÀNÍ TÓ ṢÍ SÍLẸ̀ MÚ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo ni Jon àti Sharon Schiller ṣe fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní bí wọ́n ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wọn?

  • Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn òbí bá àwọn ọmọ wọn wí ní ìbámu pẹ̀lú ipò àti ohun tí ọmọ kọ̀ọ̀kan nílò?

  • Báwo làwọn òbí ṣe lè múra ọkàn àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ láti kojú ìdánwò ìgbàgbọ́?

  • Èwo lára àwọn ohun tí ètò Jèhófà ṣe lẹ ti lò láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà?

Máa fi ìjọsìn Jèhófà sípò kìíní nínú ìdílé rẹ