ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Kí Lo Máa Yááfì fún Jèhófà?

Yorùbá
Kí Lo Máa Yááfì fún Jèhófà?
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202022251/univ/art/202022251_univ_sqr_xl.jpg
mwb22 July ojú ìwé 7

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Kí Lo Máa Yááfì fún Jèhófà?

Kí Lo Máa Yááfì fún Jèhófà?

Jèhófà pàṣẹ pé kí Dáfídì kọ́ pẹpẹ kan ní ibi ìpakà Áráúnà (2Sa 24:18)

Áráúnà sọ pé òun máa fún Dáfídì ní ilẹ̀ àtàwọn ẹran tó máa fi rúbọ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ (2Sa 24:21-23)

Dáfídì sọ pé òun ò ní rú ẹbọ tí kò ná òun ní nǹkan kan sí Jèhófà (2Sa 24:24, 25; it-1 146)

Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda àkókò wa, okun wa àtàwọn nǹkan ìní wa fún ire Ìjọba náà. (w12 1/15 18 ¶8) Àwọn nǹkan wo lo lè fi ṣe àfojúsùn ẹ kó o lè túbọ̀ máa rú “ẹbọ ìyìn” sí Jèhófà?​—Heb 13:15.