ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Fi Hàn Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Wa

Yorùbá
Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Fi Hàn Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Wa
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202021259/univ/art/202021259_univ_sqr_xl.jpg
mwb21 July ojú ìwé 13

À ń rí ọwọ́ ìfẹ́ Jèhófà lára àwọn nǹkan tó dá, torí náà ó dá wa lójú pé ó máa fi ọ̀pọ̀ ìbùkún jíǹkí wa bá a ṣe ń fi gbogbo okun wa sìn ín

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Fi Hàn Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Wa

Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Fi Hàn Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Wa

Ọwọ́ wa lè dí débi tá ò fi ní kíyè sáwọn nǹkan tí Jèhófà dá, tó jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀làwọ́ ni àti pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Àmọ́ Jésù gbà wá níyànjú pé ká máa fara balẹ̀ kíyè sí wọn, ká sì máa ronú lórí ohun tí wọ́n kọ́ wa nípa Jèhófà.​—Mt 6:25, 26.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN OHUN TÍ JÈHÓFÀ DÁ FI HÀN PÉ Ó NÍFẸ̀Ẹ́ WA, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

Báwo làwọn nǹkan yìí ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa . . .

  • àwọn èròjà tó wà láyé?

  • afẹ́fẹ́?

  • koríko?

  • àwọn ẹranko?

  • ara àwa èèyàn?

  • ọpọlọ wa?