Arákùnrin kan ń dá ọ̀dọ́kùnrin kan lẹ́kọ̀ọ́

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI July 2019

Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Ìjíròrò tó dá lórí ohun tó fà á tá a fi ń jìyà àti bí Ọlọ́run ṣe máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ wá.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ẹ Bọ́ Ìwà Àtijọ́ Sílẹ̀, Kí Ẹ sì Fi Ìwà Tuntun Wọ Ara Yín Láṣọ

Lẹ́yìn ìrìbọmi, a gbọ́dọ̀ máa báa lọ láti máa sapá kí àwọn ìwà àtíjọ́ yẹn má bàa gbérí mọ́, ká sì máa fi àwọn ìwà tuntun ṣèwà hù.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Ẹ Máa Fún Ara Yín Níṣìírí, Kí Ẹ sì Máa Gbé Ara Yín Ró”

Gbogbo àwa Kristẹni la lè fún ẹlòmí ì ní ìṣírí. Lọ́nà wo?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

A Ó Fi Arúfin Náà Hàn

A ti wá mọ àṣírí ìwà ìkà “arúfin náà” tó wà nínú ìwé 2 Tẹsalóníkà 2.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Iṣẹ́ Rere Ni Kó O Máa Lé

Ó yẹ kí àwọn ọkùnrin tó bá ti ṣèrìbọmi, títí kan àwọn tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ máa sapá láti máa ṣiṣẹ́ rere. Lọ́nà wo?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀kọ́ Wo Lo Rí Kọ́ Lára Wọn?

Tó o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà, báwo lo ṣe lè fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkùnrin tó nírìírì, kó o sì túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ìfọkànsin Ọlọ́run Tàbí Ọrọ̀

Kí nìdí tá a fi máa túbọ̀ láyọ̀ tá a bá gbájú mọ́ ìjọsìn Jèhófà dípò ọrọ̀?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ìfọkànsin Ọlọ́run Tàbí Eré Ìdárayá

Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ran àwa Kristẹni lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ́ nípa eré ìdárayá?