ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti January 5-11, 2026

Yorùbá
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti January 5-11, 2026
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202026001/univ/art/202026001_univ_sqr_xl.jpg
mwb26 January ojú ìwé 2-16

January 5-11

ÀÌSÁYÀ 17-20

January 5-11

Orin 153 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. “Ìpín Àwọn Tó Ń Kó Wa Lẹ́rù”

(10 min.)

Bíbélì fi aráyé wé omi òkun tó ń ru gùdù, tí kò ní àlàáfíà (Ais 17:12; w18.06 7 ¶16)

A mọ̀ pé àwọn èèyàn máa hùwà àìdáa sí wa torí pé a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú (Jo 15:18, 19; w16.04 22 ¶4)

Láìpẹ́, Jèhófà máa gbà wá lọ́wọ́ “àwọn tó ń kó wa lẹ́rù” (Ais 17:13, 14; ip-1 198 ¶20)

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Ais 20:2—Ṣé òótọ́ ni pé Àìsáyà rìn kiri níhòòhò fún ọdún mẹ́ta? (w06 12/1 11 ¶2)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Lo ọ̀kan nínú àwọn àkòrí tó wà ní àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn láti bá ọkọ tàbí ìyàwó kan sọ̀rọ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 3)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 4)

6. Àsọyé

(5 min.) lmd àfikún A kókó 14—Àkòrí: Ọlọ́run Fẹ́ Ká Máa Gbàdúrà sí Òun. (th ẹ̀kọ́ 8)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 148

7. “Rántí Àpáta Ààbò Rẹ”

(10 min.) Ìjíròrò.

Jèhófà ni àpáta ààbò wa. (Ais 17:10) Ó máa dáàbò bo àwọn tó bá sá lọ sọ́dọ̀ ẹ̀. (Sm 144:1, 2) Òótọ́ ni pé Jèhófà kì í yọ wá kúrò nínú gbogbo àdánwò, àmọ́ gbogbo ìgbà ló máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á.—1Kọ 10:13.

Ohun kan tá a lè ṣe táá fi hàn pé a rántí Jèhófà ni pé ká máa ṣègbọràn sí i. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà. O lè pe àwọn ọmọdé mélòó kan wá sórí pèpéle tàbí kó o bi àwọn ará pé:

  • Báwo ni Jèhófà ṣe gba àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sílẹ̀?—Da 3:24-28

  • Báwo ni Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà ṣe fi hàn pé ọ̀rẹ́ Jèhófà làwọn?

  • Ìgbà wo ló máa ń ṣòro fún ẹ láti ṣègbọràn sí Jèhófà?

  • Àwọn nǹkan wo ló máa jẹ́ kó o lè máa ṣègbọràn sí Jèhófà?

8. Máa Wáyè Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ọ̀rẹ́ Jèhófà Lójoojúmọ́

(5 min.) Ìjíròrò.

Àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń kàwé la ṣe àwọn fídíò Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ọ̀rẹ́ Jèhófà fún. Ó máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò yẹn máa ń rọ àwọn ọmọdé pé kí wọ́n “máa wáyè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà lójoojúmọ́.”

  • Kí lo lè ṣe kó o lè máa ráyè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà lójoojúmọ́?

  • Èwo nínú àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn ni wàá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ẹ̀, kí sì nìdí?

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 73 àti Àdúrà