January 26–February 1
ÀÌSÁYÀ 28-29
Orin 28 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Máa Fi Ẹnu àti Ọkàn Rẹ Bọlá fún Jèhófà
(10 min.)
Àìsáyà bá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà yẹn wí torí pé ẹnu lásán ni wọ́n fi ń sin Ọlọ́run (Ais 29:13; ip-1 299 ¶23)
Jésù mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ Àìsáyà yìí nígbà tó ń bá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé ẹ̀ wí (Mt 15:7-9; w21.05 9 ¶7)
Jèhófà fẹ́ káwọn tó ń jọ́sìn òun máa “ṣègbọràn látọkàn wá” (Ro 6:17; w24.06 10 ¶8)
Jèhófà máa ń kíyè sí wa, ó sì máa ń mọyì ẹ̀ tó bá rí i pé à ń ṣe ohun tá à ń kọ́ àwọn èèyàn
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Ais 29:1, 2—Kí nìdí tó fi bá a mu bá a ṣe pe Jerúsálẹ́mù ní Áríélì? (ip-1 296 ¶19)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Ais 29:13-24 (th ẹ̀kọ́ 2)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Gbìyànjú láti mọ ohun tẹ́ni náà nífẹ̀ẹ́ sí, kó o sì béèrè bó o ṣe lè kàn sí i nígbà míì. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 5)
5. Pa Dà Lọ
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Dáhùn ìbéèrè tẹ́ni náà béèrè nígbà tẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 10 kókó 3)
7. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(4 min.) lff ẹ̀kọ́ 18 kókó 6-7 (lmd ẹ̀kọ́ 11 kókó 3)
Orin 89
8. “Gbogbo Ìgbà Ni Mo Máa Ń Ṣe Ohun Tó Wù Ú”
(8 min.) Ìjíròrò.
Jésù sọ pé: ‘Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣe ohun tó wu Jèhófà.’ (Jo 8:29) Bíi ti Jésù, àwa náà máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ṣe nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. Ká sòótọ́ kì í fìgbà gbogbo rọrùn, àmọ́ gbogbo ìgbà tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa ń ṣe wá láǹfààní.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Ṣe Nǹkan Lọ́nà tí Jèhófà Fẹ́. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Táwọn èèyàn bá ṣenúnibíni sí wa, tí wọ́n bá fẹ́ ká ṣèṣekúṣe tàbí táwa fúnra wa bá kíyè sí pé a ti ń gbéra ga, àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ṣe nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́?
9. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ
(7 min.)
10. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 56, ọ̀rọ̀ ìṣáájú apá 10 àti ẹ̀kọ́ 57

