January 19-25
ÀÌSÁYÀ 24-27
Orin 159 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. “Ọlọ́run Wa Nìyí!”
(10 min.)
Inú wa dùn pé Jèhófà ni Ọlọ́run wa (Ais 25:9; cl 15 ¶21)
Ọ̀pọ̀ nǹkan rere la máa gbádùn nínú ayé tuntun, títí kan ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ aládùn (Ais 25:6; w24.12 6 ¶14)
Ó máa fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun (Ais 25:7, 8; w25.01 28-29 ¶11-12)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ, ‘Ta ni mo lè sọ àwọn ìlérí Jèhófà fún lọ́sẹ̀ yìí?’
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Ais 24:2—Kí nìdí tí ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ ẹsẹ yìí nínú Bíbélì tá a tún ṣe fi yàtọ̀ sí ti Bíbélì tá à ń lò tẹ́lẹ̀? (w15 12/15 17 ¶2-4)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Ais 25:1-9 (th ẹ̀kọ́ 10)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Fọgbọ́n wádìí ohun tó ń jẹ ẹni náà lọ́kàn, kó o sì fi bó ṣe lè rí ohun tó máa ràn án lọ́wọ́ hàn án lórí ìkànnì jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 3)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Lo ọ̀kan nínú àwọn àkòrí tó wà ní àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn láti bá ẹni náà sọ̀rọ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kóko 4)
6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(5 min.) Àṣefihàn. ijwbq àpilẹ̀kọ 160—Àkòrí: Kí Nìdí Tí A Fi Pe Jésù Ní Ọmọ Ọlọ́run? (th ẹ̀kọ́ 3)
Orin 144
7. Gbára Lé Jèhófà Pátápátá Tó O Bá Fẹ́ Gba Ìtọ́jú Nílé Ìwòsàn Tàbí Tó O Fẹ́ Ṣiṣẹ́ Abẹ
(15 min.) Ìjíròrò.
Jèhófà máa ń dáàbò bo ‘àwọn tó gbára lé e pátápátá.’ (Ka Àìsáyà 26:3.) Tá a bá fẹ́ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn, a lè fi hàn pé a gbára lé Jèhófà pátápátá tá a bá ń lo àwọn nǹkan tí ètò ẹ̀ ti pèsè fún wa.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Ìtọ́jú Pàjáwìrì? Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Àwọn nǹkan mẹ́ta wo ni ètò Ọlọ́run ní ká ṣe ká tó lọ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn?
-
Báwo ni onírúurú ìsọfúnni tí ètò Ọlọ́run ti fún wa a nípa ọ̀rọ̀ ìtọ́jú ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
-
Ìgbà wo ló yẹ ká kàn sí Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn?
-
Báwo ni ètò onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà pèsè yìí ṣe rí lára ẹ?
“Àlàáfíà tí kò lópin” tí Jèhófà ṣèlérí ní Àìsáyà 26:3 ò túmọ̀ sí pé a ò ní ṣàìsàn rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ètò ìrànwọ́ tí Jèhófà ti pèsè yìí máa ń jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀, kí ara sì tù wá lásìkò tá a bá ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn.
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 54-55
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | àti Àdúrà
a O lè gba àwọn ìsọfúnni yìí lọ́wọ́ àwọn alàgbà nígbà tó o bá nílò ẹ̀. Ìsọfúnni fún Àwọn Aláboyún (S-401), Ìsọfúnni fún Àwọn tó Nílò Iṣẹ́ Abẹ Tàbí Ìtọ́jú Chemotherapy (S-407) àti Báwọn Òbí Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Wọn Kí Wọ́n Má Bàá Fa Ẹ̀jẹ̀ sí Wọn Lára (S-55).

