February 23–March 1
ÀÌSÁYÀ 38-40
Orin 4 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
Olùṣọ́ àgùntàn kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́ gbé àgùntàn kan mọ́ra, ó sì ń ṣìkẹ́ ẹ̀
1. “Ó Máa Bójú Tó Agbo Ẹran Rẹ̀ Bíi Ti Olùṣọ́ Àgùntàn”
(10 min.)
Jèhófà fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ká lè túbọ̀ sún mọ́ ọn (Ais 40:8; w23.02 2-3 ¶3-4)
Ó ń bójú tó wa, ó sì tún ń ṣìkẹ́ wa (Ais 40:11; cl 70 ¶7)
Ó mọ̀ wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da àwọn ìsòro wa (Ais 40:26-29; w18.01 8 ¶4-6)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Kí ni Àìsáyà 40:11 sọ tó jẹ́ kó o túbọ̀ mọyì bí Jèhófà ṣe ń bójú tó wa?
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Ais 40:3—Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣe ṣẹ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní? (ip-1 400 ¶7)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Ais 40:21-31 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Lo àǹfààní tó bá yọ láti jẹ́ kẹ́ni náà mọ àwọn ohun tó o kọ́ nípàdé láìpẹ́ yìí. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Lo àǹfààní tó bá yọ láti jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ nípa bó o ṣe máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 4)
6. Pa Dà Lọ
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 5)
7. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(5 min.) lff kókó pàtàkì ní ẹ̀kọ́ 18, kí lo rí kọ́? àti ohun tó yẹ kó o ṣe. Fi àpilẹ̀kọ kan lápá “Ṣèwádìí” ṣàlàyé fún ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kó lè mọ̀ pé òótọ́ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ara wa. (lmd ẹ̀kọ́ 11 kókó 3)
Orin 160
8. Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdọọdún
(15 min.) Ìjíròrò.
Kọ́kọ́ ka lẹ́tà látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ọdọọdún. Jẹ́ kí àwọn ará sọ ohun tó wú wọn lórí nínú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kárí Ayé ti Ọdún 2025. Lẹ́yìn náà, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde kan tó o ti yàn, kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá.
Based on NASA/Visible Earth imagery
Lọ́dún 2025, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fìtara wàásù láti ilé dé ilé, a sì kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
-
Kí ló wú ẹ lórí nínú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdún 2025?
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 64-65

