ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti February 16-22, 2026

Yorùbá
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti February 16-22, 2026
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202026007/univ/art/202026007_univ_sqr_xl.jpg
mwb26 January ojú ìwé 12-13

February 16-22

ÀÌSÁYÀ 36-37

February 16-22

Orin 150 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. “Má Bẹ̀rù Nítorí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí O Gbọ́”

(10 min.)

Rábúṣákè lọ sí Jerúsálẹ́mù kó lè dẹ́rù ba àwọn èèyàn Jèhófà (Ais 36:1, 2; it “Hẹsikáyà” No. 1 ¶14)

Ó fẹ́ kó jìnnìjìnnì bá wọn, kí wọ́n sì rò pé kò sẹ́ni tó lè gbà wọ́n (Ais 36:8; ip-1 387 ¶10)

Ó ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ torí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àti Hẹsikáyà ọba wọn (Ais 36:7, 18-20; ip-1 388 ¶13-14)

Kò sídìí tó fi yẹ káwa èèyàn Jèhófà máa bẹ̀rù àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ wa.—Ais 37:6, 7

OHUN TẸ́ Ẹ LÈ ṢE NÍGBÀ ÌJỌSÌN ÌDÍLÉ: Ẹ wo FÍDÍÒ náà “Jèhófà . . . Ìwọ Ni Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé,” kẹ́ ẹ sì jíròrò ohun tẹ́ ẹ kọ́ níbẹ̀.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Ais 37:29—Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Jèhófà sọ pé òun máa fi ìjánu sáàárín ètè Ọba Senakérúbù? (it “Ìjánu” ¶4)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Lo ọ̀kan nínú àwọn àkòrí tó wà ní àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn láti bá ẹni náà sọ̀rọ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 5)

6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́

(5 min.) Àṣefihàn. ijwbq àpilẹ̀kọ 110 ¶1-4—Àkòrí: Kí Ni Ìrìbọmi Túmọ̀ Sí? (th ẹ̀kọ́ 17)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 118

7. “Kí Lo Gbọ́kàn Lé?”

(15 min.) Ìjíròrò.

Ṣé ẹnì kan ti fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ rí torí pé o gba Ọlọ́run gbọ́ tàbí torí pé o gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́? Ṣé wọ́n ti bú ẹ rí torí pé o jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù lè bẹ̀rẹ̀ sí í bà ẹ́, kó o má sì mọ ohun tó o máa sọ. Kódà irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú kó o máa ṣiyèméjì. Kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa bẹ̀rù tàbí ṣiyèméjì?

Ka Àìsáyà 36:4. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì kí ohun tá a gbà gbọ́ dá wa lójú?

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ìgbà Ọ̀dọ́ Mi—Ṣé Ó Bọ́gbọ́n Mu Ká Gbà Pé Ọlọ́run Wà? Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí ni Elibaldo àti Crystal ṣe kí ohun tí Bíbélì sọ lè túbọ̀ dá wọn lójú?

  • Kí ló jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run wà?

  • Àwọn ẹsẹ Bíbélì wo ló jẹ́ kó dá ẹ lójú pé . . .

    Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ?

    gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́?

    o ti rí ìsìn tòótọ́?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 9 àti Àdúrà