ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Àbájáde Irọ́ Àkọ́kọ́

Yorùbá
Àbájáde Irọ́ Àkọ́kọ́
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202020006/univ/art/202020006_univ_sqr_xl.jpg
mwb20 January ojú ìwé 4

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 3-5

Àbájáde Irọ́ Àkọ́kọ́

Àbájáde Irọ́ Àkọ́kọ́

3:1-6, 15-19

Àtìgbà tí Sátánì ti parọ́ fún Éfà ló ti ń ṣi aráyé lọ́nà. (Ifi 12:9) Báwo làwọn irọ́ tí Sátánì pa tó wà nísàlẹ̀ yìí ṣe mú kó ṣòro fáwọn èèyàn láti sún mọ́ Jèhófà?

  • Kò sí Ọlọ́run

  • Mẹ́talọ́kan ni Ọlọ́run

  • Ọlọ́run ò lórúkọ

  • Ọlọ́run máa fi iná ọ̀run àpáàdì dá àwọn èèyàn lóró títí láé

  • Àmúwá Ọlọ́run ni gbogbo ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí wa

  • Ọlọ́run ò rí tiwa rò

Báwo làwọn irọ́ yìí ṣe rí lára rẹ?

Kí lo lè ṣe láti gbèjà orúkọ Ọlọ́run?