Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 25-26

Pọ́ọ̀lù Ké Gbàjarè sí Késárì Ó sì Wàásù fún Ọba Hẹ́rọ́dù Àgírípà

Pọ́ọ̀lù Ké Gbàjarè sí Késárì Ó sì Wàásù fún Ọba Hẹ́rọ́dù Àgírípà

25:11; 26:​1-3, 28

Lóòótọ́ kò yẹ ká máa ṣàníyàn nípa ohun tá a máa sọ tí wọ́n bá mú wa wá “síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba,” àmọ́ ó yẹ ká “wà ní ìmúratán” láti gbèjà ara wa níwájú ẹni tó bá béèrè nípa ìrètí wa. (Mt 10:18-20; 1Pe 3:15) Tí àwọn tó ń ta kò wá bá “fi àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n,” báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù?​—Sm 94:20.

  • A máa lo ẹ̀tọ́ wa lábẹ́ òfin láti gbèjà ìhìn rere.​—Iṣe 25:11

  • A máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ tá a bá ń bá wọn sọ̀rọ̀.​—Iṣe 26:​2, 3

  • Tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, a máa sọ bí ìhìn rere náà ṣe ran àwa àtàwọn míì lọ́wọ́.​—Iṣe 26:​11-20