Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 29-33

“Ọba Kan Yóò Jẹ fún Òdodo”

“Ọba Kan Yóò Jẹ fún Òdodo”

Jésù tó jẹ́ Ọba wa, fún wa ní “àwọn ọmọ aládé,” ìyẹn àwọn alàgbà, tó ń bójú tó agbo Ọlọ́run

32:1-3

  • Wọ́n dà bí “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù,” torí pé wọ́n ń dáàbò bo agbo lọ́wọ́ inúnibíni àti ìrẹ̀wẹ̀sì tó dà bí ìjì líle

  • Wọ́n dà “bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi,” ní ti pé wọ́n ń pèsè ìtura fún àwọn tí òǹgbẹ tẹ̀mí ń gbẹ. Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ń kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí kò lábùlà

  • Wọ́n dà “bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú,” torí pé wọ́n ń ran agbo Ọlọ́run lọ́wọ́ láti rí ìtura àti ìtọ́sọ́nà tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run