Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

“Jìófà . . . Ìwọ Ni Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé”

“Jìófà . . . Ìwọ Ni Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé”

Ó ṣe pàtàkì pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lásìkò tó rọgbọ àti nígbà tí nǹkan bá nira. (Sm 25:1, 2) Ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù tó wà ní Júdà dojú kọ ìṣòro kan tó dán ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọ́run wò. A rí ẹ̀kọ́ tó pọ̀ kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn. (Ro 15:4) Lẹ́yìn tó o bá ti wo fídíò náà Jèhófà . . . Ìwọ Ni Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé,” gbìyànjú láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Ìṣòro wo ni Hesekáyà dojú kọ?

  2. Báwo ni Hesekáyà ṣe fi ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Òwe 22:3 sílò nígbà tó kíyè sí i pé ó ṣeé ṣe káwọn Ásíríà sàga ti àwọn?

  3. Kí nìdí tí Hesekáyà kò fi ronú pé káwọn juwọ́ sílẹ̀ fún Ásíríà tàbí kí òun wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Íjíbítì?

  4. Báwo ni Hesekáyà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn Kristẹni?

  5. Kí lóhun tó lè dán ìgbọ́kànlé wa nínú Jèhófà wò lóde òní?

Kọ àwọn ipò tó o ti lè fi hàn pé Jèhófà lo gbọ́kàn lé jù lọ