Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 29-32

Ìjọsìn Tòótọ́ Gba Ìsapá

Ìjọsìn Tòótọ́ Gba Ìsapá

Hesekáyà fẹ́ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ṣe ìjọsìn tòótọ́, ó sì ṣàṣeyọrí

29:10-17

 • 746 sí 716 Ṣ.S.K.

  Ìṣàkóso Hesekáyà

 • NÍSÀN 746 Ṣ.S.K.

  • Ọjọ́ 1 sí 8: Ó sọ àgbàlá inú lọ́hùn-ún di mímọ́

  • Ọjọ́ 9 sí 16: Ó fọ ilé Jèhófà mọ́

  • Ètùtù fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ìmúbọ̀sípò ìjọsìn tòótọ́ bẹ̀rẹ̀

 • 740 Ṣ.S.K.

  Samáríà pa run

Hesekáyà ní kí gbogbo àwọn tó lọ́kàn rere pé jọ láti jọ́sìn Ọlọ́run

30:5, 6, 10-12

 • Ó ní kí àwọn sárésáré pín lẹ́tà tó fi ṣèfilọ̀ Ìrékọjá jákèjádò ilẹ̀ náà, láti Bíá-ṣébà dé Dánì

 • Àwọn kan fi wọ́n ṣẹ̀sín, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló wá síbi Ìrékọjá náà