ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

“Wò Ó! Mò Ń Sọ Ohun Gbogbo di Tuntun”

Yorùbá
“Wò Ó! Mò Ń Sọ Ohun Gbogbo di Tuntun”
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202019452/univ/art/202019452_univ_sqr_xl.jpg
mwb19 December ojú ìwé 6

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌFIHÀN 20-22

“Wò Ó! Mò Ń Sọ Ohun Gbogbo di Tuntun”

“Wò Ó! Mò Ń Sọ Ohun Gbogbo di Tuntun”

21:1-5

Jèhófà ṣèlérí pé òun máa sọ ohun gbogbo di tuntun.

  • “Ọ̀run tuntun”: Ìjọba tuntun kan tó máa mú kí òdodo gbilẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé

  • “Ayé tuntun”: Àwọn èèyàn tó fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò nígbèésí ayé wọn

  • “Ohun gbogbo di tuntun”: Gbogbo ẹ̀dùn ọkàn, ìrora àtàwọn nǹkan míì tó ń fa ìbànújẹ́ máa pòórá, ojoojúmọ́ sì ni ìgbésí ayé wa á máa dùn bí oyin