Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

December 5-11

AÍSÁYÀ 1-5

December 5-11
 • Orin 107 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Ẹ Jẹ́ Kí A Gòkè Lọ sí Òkè Ńlá Jèhófà”: (10 min.)

  • [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Aísáyà.]

  • Ais 2:2, 3—“Òkè ńlá ilé Jèhófà” dúró fún ìjọsìn tòótọ́ (ip-1 ojú ìwé 38 sí 41 ìpínrọ̀ 6 sí 11 àti ojú ìwé 44 àti 45 ìpínrọ̀ 20 àti 21)

  • Ais 2:4—Àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà kò kọ́ṣẹ́ ogun jíjà mọ́ (ip-1 ojú ìwé 46 àti 47 ìpínrọ̀ 24 àti 25)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Ais 1:8, 9—Ọ̀nà wo la ó gbà fi ọmọbìnrin Síónì “sílẹ̀ bí àtíbàbà inú ọgbà àjàrà”? (w06 12/1 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 5)

  • Ais 1:18—Kí ni ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a mú àwọn ọ̀ràn tọ́ láàárín wa”? (w06 12/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1; it-2-E ojú ìwé 761 ìpínrọ̀ 3)

  • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

  • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

 • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ais 5:1-13

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

 • Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò tó dá lórí “Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò.” Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú láti kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn sílẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI