ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ẹ Dúró Gbọn-in Bí Òpin Ṣe Ń Sún Mọ́lé

Yorùbá
Ẹ Dúró Gbọn-in Bí Òpin Ṣe Ń Sún Mọ́lé
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202020284/univ/art/202020284_univ_sqr_xl.jpg
mwb20 August ojú ìwé 3

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ Dúró Gbọn-in Bí Òpin Ṣe Ń Sún Mọ́lé

Ẹ Dúró Gbọn-in Bí Òpin Ṣe Ń Sún Mọ́lé

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Láìpẹ́, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì máa dán wa wò, ìyẹn á sì fi hàn bóyá a nígboyà àti ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà. Ìparun ìsìn èké ló máa bẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá. (Mt 24:21; Ifi 17:​16, 17) Lákòókò tí nǹkan máa lé ganan yẹn, ó ṣeé ṣe ká máa kéde ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tó dà bí òkúta yìnyín. (Ifi 16:21) Lẹ́yìn náà, Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù máa gbéjà kò wá. (Isk 38:​10-12, 14-16) Ìyẹn ló máa mú kí Jèhófà gbégbèésẹ̀, kí “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” sì bẹ̀rẹ̀. (Ifi 16:​14, 16) Tá a bá ń fìgboyà kojú àwọn ohun tó lè dán ìgbàgbọ́ wa wò ní báyìí, àá túbọ̀ nígboyà láti kojú àwọn ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Fìgboyà dúró lórí àwọn ìlànà Jèhófà nípa ìwà rere.​—Ais 5:20

  • Máa jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará.​—Heb 10:​24, 25

  • Máa tẹ̀ lé ìlànà èyíkéyìí tí ètò Ọlọ́run bá fún wa láìjáfara.​—Heb 13:17

  • Máa ronú lórí bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ là nígbà àtijọ́.​—2Pe 2:9

  • Máa gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e.​—Sm 112:​7, 8

WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN OHUN TÓ MÁA ṢẸLẸ̀ LỌ́JỌ́ IWÁJÚ TÓ GBA PÉ KÁ NÍ ÌGBOYÀ​—ÀYỌLÒ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àdánwò wo làwọn àkéde kan kojú nígbà tí ìjọ wọn pín sí méjì?

  • Tá a bá ń ṣègbọràn, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ nígboyà?

  • Kí nìdí tá a fi máa nílò ìgboyà nígbà tí Amágẹ́dọ́nì bá dé?

  • Múra sílẹ̀ ní báyìí bó o ṣe ń retí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú tó máa gba pé ká nígboyà

    Ìtàn Bíbélì wo ló lè mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa gbà wá là?​—2Kr 20:​1-24