ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Àwọn Tó Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Máa Ń Faṣẹ́ Lé Àwọn Míì Lọ́wọ́

Yorùbá
Àwọn Tó Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Máa Ń Faṣẹ́ Lé Àwọn Míì Lọ́wọ́
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202020289/univ/art/202020289_univ_sqr_xl.jpg
mwb20 August ojú ìwé 6

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 17-18

Àwọn Tó Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Máa Ń Faṣẹ́ Lé Àwọn Míì Lọ́wọ́

Àwọn Tó Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Máa Ń Faṣẹ́ Lé Àwọn Míì Lọ́wọ́

18:17, 18, 21, 22, 24, 25

Kí ètò Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú, àwọn arákùnrin tó nírìírí máa ń fìfẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ dá àwọn tó kéré lọ́jọ́ orí lẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n á faṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́. Ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀?

  • Fara balẹ̀ kíyè sí àwọn tó lẹ́mìí tó dáa, tí wọ́n sì ń nàgà fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn

  • Fara balẹ̀ ṣàlàyé ohun tí wọ́n máa ṣe kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tẹ́ ẹ bá yàn fún wọn láṣeyọrí

  • Fún wọn ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò fún iṣẹ́ náà

  • Máa kíyè sí bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú, kó o sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé o fọkàn tán wọn

BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn iṣẹ́ wo ni mo lè fà lé àwọn míì lọ́wọ́?’