Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jésù Kú fún Àwọn Arákùnrin Rẹ Náà

Jésù Kú fún Àwọn Arákùnrin Rẹ Náà

Jésù fẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ fún àwa èèyàn aláìpé. (Ro 5:8) Abájọ tí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan fi mọ rírì ìfẹ́ tí Jésù fi hàn nípa bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Síbẹ̀, ó yẹ ká máa rántí pé àwa nìkan kọ́ ni Kristi kú fún. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní irú ìfẹ́ tí Kristi ní sáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ aláìpé bíi tiwa? Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́ta yẹ̀ wò. Lákọ̀ọ́kọ́, a lè yan àwọn míì lọ́rẹ̀ẹ́, irú bíi àwọn tí ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ wọn dàgbà yàtọ̀ sí tiwa. (Ro 15:7; 2Kọ 6:​12, 13) Ìkejì ni pé, ó yẹ ká máa ṣọ́ra ká má bàa sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun tó máa bí àwọn míì nínú. (Ro 14:​13-15) Ní paríparí ẹ̀, tí àwọn míì bá ṣẹ̀ wá, ó yẹ ká máa tètè dárí jì wọ́n. (Lk 17:​3, 4; 23:34) Tá a bá sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ní àwọn ọ̀nà yìí, Jèhófà máa jẹ́ kí ìjọ wà ní ìṣọ̀kan àti ní àlááfíà.

WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA SUNWỌ̀N SÍ I LÓJOOJÚMỌ́! KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Èrò wo ni Miki kọ́kọ́ ní nípa ìjọ rẹ̀?

  • Kí ló mú kí èrò rẹ̀ yí pa dà?

  • Báwo ni àpẹẹrẹ Jésù ṣe ran Miki lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ́? (Mk 14:38)

  • Báwo ni Òwe 19:11 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ́ nípa àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa?