MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àwọn Ànímọ́ Kristẹni Tó Yẹ Kó O Ní—Ìgboyà
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ:
-
A gbọ́dọ̀ ní ìgboyà ká tó lè wàásù. —Iṣe 5:27-29, 41, 42
-
Ìpọ́njú ńlá máa fi hàn bóyá a ní ìgboyà.—Mt 24:15-21
-
Ìbẹ̀rù èèyàn máa ń yọrí sí wàhálà. —Jer 38:17-20; 39:4-7
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
-
Ṣàṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ là.—Ẹk 14:13
-
Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ìgboyà. —Iṣe 4:29, 31
-
Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.—Sm 118:6
Àwọn nǹkan wo ló máa ń bà mí lẹ́rù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, báwo ni mo sì ṣe lè borí àwọn ìbẹ̀rù náà?
WO FÍDÍÒ NÁÀ, YẸRA FÚN OHUN TÓ LÈ BA ÌDÚRÓṢINṢIN RẸ JẸ́—ÌBẸ̀RÙ ÈÈYÀN, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ní ìgboyà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
-
Ohun méjì tó yàtọ̀ síra wo ló wà nínú Òwe 29:25?
-
Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa fi ìgboyà ṣe ìfẹ́ Jèhófà nísinsìnyí?

