ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ni Kó O Máa Lé

Yorùbá
Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ni Kó O Máa Lé
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202019130/univ/art/202019130_univ_sqr_xl.jpg

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ni Kó O Máa Lé

Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ni Kó O Máa Lé

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Olùkọ́ Atóbilọ́lá ni Jèhófà, ó ń fún wa ní ẹ̀kọ́ tó dáa jù lọ. Ó ń kọ́ wa bá a ṣe lè gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀, ó sì ń múra wa sílẹ̀ fún ọjọ́ iwájú aláyọ̀ tá à ń retí, gbogbo èyí ló ń ṣe fún wa lọ́fẹ̀ẹ́! (Ais 11:​6-9; 30:​20, 21; Ifi 22:17) Jèhófà tún ń lo ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá yìí láti múra wa sílẹ̀ fún iṣẹ́ tó ń gbẹ̀mí là tá à ń ṣe lónìí.​—2Kọ 3:5.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Sapá láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti oníwà pẹ̀lẹ́.​—Sm 25:​8, 9

  • Máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ báyìí, irú bí iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́, ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀

  • Ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí.​—Flp 3:13

  • Yááfì àwọn nǹkan, kó o bàa lè tóótun láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i.​—Flp 3:8

WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ̀KỌ́ JÈHÓFÀ SỌ WÁ DI ỌLỌ́RỌ̀ NÍPA TẸ̀MÍ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Irú àwọn ìṣòro wo ni àwọn akéde kan ti borí kí wọ́n lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run?

  • Irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ni àwọn tó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run máa ń rí gbà?

  • Nígbà tí àwọn tó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí dé ibi iṣẹ́ àyànfúnni wọn, báwo ni àwọn ará ìjọ ibẹ̀ ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?

  • Kí ni ẹni tó bá fẹ́ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run gbọ́dọ̀ dójú ìlà ẹ̀? (kr 189)

  • Èwo nínú àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ míì tí ètò Ọlọ́run pèsè lo tún lè fi ṣe àfojúsùn rẹ?

Àwọn ìbùkún wo lo máa rí tó o bá fi ṣe àfojúsùn rẹ láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run?