Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Fún Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Níṣìírí

Fún Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Níṣìírí

Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ ló máa ń wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Àwọn náà ń sáré ìyè nígbà kan, àmọ́ oríṣiríṣi nǹkan ló lè fà á tí wọ́n fi wá dẹwọ́ báyìí, a sì sọ̀rọ̀ nipa díẹ̀ lára àwọn ìdí yìí nínú ìwé pẹlẹbẹ náà Jọ̀wọ́ Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà. (Heb 12:1) Síbẹ̀, àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ ṣì ṣeyebíye lójú Jèhófà, torí pé ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ló fi rà wọ́n. (Iṣe 20:28; 1Pe 1:18, 19) Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà?

Bó ṣe jẹ́ pé olùṣọ́ àgùntàn máa ń sapá gidigidi láti wá àgùntàn tó bá sú lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn alàgbà ṣe máa ń wá àwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́, wọ́n sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. (Lk 15:4-7) Èyí fi hàn pé Jèhófà ń fìfẹ́ bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀. (Jer 23:3, 4) Kì í ṣe àwọn alàgbà nìkan ló yẹ kó máa fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ níṣìírí o, iṣẹ́ gbogbo wa ni. Tá a bá sapá láti fìfẹ́ hàn sí wọn tá a sì gba tiwọn rò, inú Jèhófà máa dùn, ó sì máa san wá lẹ́san rere. (Owe 19:17; Iṣe 20:35) Torí náà, ronú nípa àwọn tó o lè fún níṣìírí, má sì jáfara láti ṣe bẹ́ẹ̀!

WO FÍDÍÒ NÁÀ, Ẹ MÁA FÁWỌN ALÁÌṢIṢẸ́MỌ́ NÍṢÌÍRÍ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ni Abbey ṣe nígbà tó pàdé Ẹlẹ́rìí kan tí kò mọ̀ rí?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká sọ fún àwọn alàgbà tá a bá fẹ́ ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́?

  • Kí ni Abbey ṣe kó tó lọ sọ́dọ̀ Laura lẹ́ẹ̀kejì?

  • Báwo ni Abbey ṣe fi hàn pé òun ní ìforítì, sùúrù àti ìfẹ́ nígbà tó ń ran Laura lọ́wọ́?

  • Kí la rí kọ́ látinú àkàwé Jésù tó wà ní Lúùkù 15:8-10?

  • Kí ló jẹ́ àbájáde bí Abbey, àwọn alàgbà àtàwọn míì ṣe ran Laura lọ́wọ́?