Yorùbá
‘Ẹ Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́, Ẹ Má Ṣe Rìn Nípa Ohun Tí Ẹ̀ Ń Rí’
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/ivwf/univ/pt/ivwf_univ_lg.jpg

‘Ẹ Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́, Ẹ Má Ṣe Rìn Nípa Ohun Tí Ẹ̀ Ń Rí’

Àwọn ọmọ ogun Róòmù gbógun yí Jerúsálẹ́mù ká, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n kúrò. Ó wá gba kí ìdílé Kristẹni méjì ṣe ìpinnu tó lágbára. Ṣé ohun tí Jésù ní kí wọ́n ṣe ni wọ́n á ṣe, kí wọ́n sì fi gbogbo ohun tí wọ́n ti mọwọ́ ẹ̀ sílẹ̀ pátápátá? Ohun tí wọ́n bá ṣe máa pinnu bóyá wọ́n á yè é àbí ẹ̀mí wọn á lọ sí i. Fídíò yìí dá lórí àwọn ohun kan tí Bíbélì sọ pé ó ṣẹlẹ̀, tó sì bá ohun tí àwọn òpìtàn sọ mu. Kó lè rí bó ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an nígbà yẹn, ẹ máa rí ibi táwọn èèyàn ti ń jà nínú fídíò yìí; àmọ́ kì í ṣe ohun tá à ń sọ ni pé ó dáa ká máa wo fíìmù tí wọ́n ti ń hùwà ìpa, a kàn fẹ́ kẹ́ ẹ mọ ohun tójú àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní rí ni.