Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Jeremáyà

Orí

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

 • 1

  • Ọlọ́run yan Jeremáyà láti jẹ́ wòlíì (1-10)

  • Ìran nípa igi álímọ́ńdì (11, 12)

  • Ìran nípa ìkòkò ìsebẹ̀ (13-16)

  • Ọlọ́run fún Jeremáyà lágbára kó lè jẹ́ iṣẹ́ tó rán an (17-19)

 • 2

  • Ísírẹ́lì fi Jèhófà sílẹ̀ láti lọ jọ́sìn àwọn ọlọ́run míì (1-37)

   • Ísírẹ́lì dà bí àjàrà ilẹ̀ òkèèrè (21)

   • Ẹ̀jẹ̀ ta sí i láṣọ (34)

 • 3

  • Bí ìpẹ̀yìndà Ísírẹ́lì ṣe burú tó (1-5)

  • Ísírẹ́lì àti Júdà jẹ̀bi àgbèrè (6-11)

  • Ọlọ́run ní kí wọ́n ronú pìwà dà (12-25)

 • 4

  • Ìrònúpìwàdà ń mú ìbùkún wá (1-4)

  • Àjálù yóò wá láti àríwá (5-18)

  • Àjálù tó ń bọ̀ kó ẹ̀dùn ọkàn bá Jeremáyà (19-31)

 • 5

  • Àwọn èèyàn náà kò gba ìbáwí Jèhófà (1-13)

  • Ìparun ń bọ̀, àmọ́ kì í ṣe ìparun pátápátá (14-19)

  • Jèhófà pe àwọn èèyàn náà wá jíhìn (20-31)

 • 6

  • Ọ̀tá máa tó dó ti Jerúsálẹ́mù (1-9)

  • Ìbínú Jèhófà lórí Jerúsálẹ́mù (10-21)

   • Wọ́n ń sọ pé “Àlàáfíà!” nígbà tí kò sí àlàáfíà (14)

  • Ọ̀tá ya wọ ilẹ̀ náà láti àríwá (22-26)

  • Jeremáyà máa di ẹni tó ń yọ́ wúrà àti fàdákà mọ́ (27-30)

 • 7

  • Ìgbẹ́kẹ̀lé asán nípa tẹ́ńpìlì Jèhófà (1-11)

  • Tẹ́ńpìlì náà yóò dà bíi Ṣílò (12-15)

  • Ọlọ́run kọ ìjọsìn wọn (16-34)

   • Wọ́n jọ́sìn “Ọbabìnrin Ọ̀run” (18)

   • Wọ́n ń fi ọmọ rúbọ ní Hínómù (31)

 • 8

  • Àwọn èèyàn náà ń ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe (1-7)

  • Ǹjẹ́ ọgbọ́n lè wà láìsí ọ̀rọ̀ Jèhófà? (8-17)

  • Jeremáyà kédàárò lórí ìṣubú Júdà (18-22)

   • “Ṣé kò sí básámù ní Gílíádì ni?” (22)

 • 9

  • Ìbànújẹ́ Jeremáyà pọ̀ gan-an (1-3a)

  • Jèhófà pe Júdà wá jíhìn (3b-16)

  • Ìdárò lórí Júdà (17-22)

  • Máa yangàn torí pé o mọ Jèhófà (23-26)

 • 10

  • Àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè àti Ọlọ́run alààyè (1-16)

  • Ìparun àti ìgbèkùn ń bọ̀ lọ́nà (17, 18)

  • Inú Jeremáyà bà jẹ́ (19-22)

  • Àdúrà tí wòlíì náà gbà (23-25)

   • Èèyàn kò lè darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀ (23)

 • 11

  • Júdà da májẹ̀mú Ọlọ́run (1-17)

   • Àwọn ọlọ́run pọ̀ bí ìlú ṣe pọ̀ (13)

  • Jeremáyà dà bí ọ̀dọ́ àgùntàn tí wọ́n fẹ́ lọ pa (18-20)

  • Àtakò tí àwọn ará ìlú Jeremáyà ṣe (21-23)

 • 12

  • Jeremáyà mú ẹjọ́ rẹ̀ wá (1-4)

  • Ohun tí Jèhófà sọ (5-17)

 • 13

  • Àmùrè aṣọ ọ̀gbọ̀ tó bà jẹ́ (1-11)

  • Ọlọ́run máa fọ́ àwọn ìṣà wáìnì (12-14)

  • Júdà alágídí máa lọ sí ìgbèkùn (15-27)

   • “Ǹjẹ́ ọmọ Kúṣì lè yí àwọ̀ rẹ̀ pa dà?” (23)

 • 14

  • Ọ̀dá, ìyàn àti idà (1-12)

  • Ọlọ́run dá àwọn wòlíì èké lẹ́bi (13-18)

  • Jeremáyà sọ ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn èèyàn náà dá (19-22)

 • 15

  • Jèhófà kò ní yí ìdájọ́ rẹ̀ pa dà (1-9)

  • Jeremáyà mú ẹjọ́ rẹ̀ wá (10)

  • Ohun tí Jèhófà sọ (11-14)

  • Àdúrà Jeremáyà (15-18)

   • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ mú kí inú rẹ̀ dùn (16)

  • Jèhófà fún Jeremáyà lágbára (19-21)

 • 16

  • Jeremáyà kò gbọ́dọ̀ gbéyàwó tàbí kó ṣọ̀fọ̀, kò sì gbọ́dọ̀ jẹ àsè (1-9)

  • Ìjìyà, lẹ́yìn náà ìpadàbọ̀sípò (10-21)

 • 17

  • Júdà ti jingíri sínú ẹ̀ṣẹ̀ (1-4)

  • Ìbùkún tó wà nínú gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà (5-8)

  • Ọkàn tó ń tanni jẹ (9-11)

  • Jèhófà jẹ́ ìrètí Ísírẹ́lì (12, 13)

  • Àdúrà Jeremáyà (14-18)

  • Jẹ́ kí Sábáàtì wà ní mímọ́ (19-27)

 • 18

  • Amọ̀ tó wà lọ́wọ́ amọ̀kòkò (1-12)

  • Jèhófà kẹ̀yìn sí Ísírẹ́lì (13-17)

  • Wọ́n gbìmọ̀ ibi sí Jeremáyà; ó ké pe Ọlọ́run (18-23)

 • 19

  • Ọlọ́run sọ pé kí Jeremáyà fọ́ ṣágo amọ̀ (1-15)

   • Wọ́n fi ọmọ rúbọ sí Báálì (5)

 • 20

  • Páṣúrì lu Jeremáyà (1-6)

  • Jeremáyà ò lè dákẹ́ ìwàásù (7-13)

   • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bí iná tó ń jó (9)

   • Jèhófà dà bíi jagunjagun tó ń bani lẹ́rù (11)

  • Jeremáyà mú ẹjọ́ rẹ̀ wá (14-18)

 • 21

  • Jèhófà kọ ẹ̀bẹ̀ Sedekáyà (1-7)

  • Àwọn èèyàn yóò yan ikú tàbí ìyè (8-14)

 • 22

  • Ọ̀rọ̀ ìdájọ́ sí àwọn ọba búburú (1-30)

   • Nípa Ṣálúmù (10-12)

   • Nípa Jèhóákímù (13-23)

   • Nípa Konáyà (24-30)

 • 23

  • Àwọn olùṣọ́ àgùntàn rere àti búburú (1-4)

  • Ààbò lábẹ́ “èéhù kan tí ó jẹ́ olódodo” (5-8)

  • Ọlọ́run dá àwọn wòlíì èké lẹ́bi (9-32)

  • “Ẹrù tó wúwo” látọ̀dọ̀ Jèhófà (33-40)

 • 24

  • Àwọn ọ̀pọ̀tọ́ tó dára àtèyí tó ti bà jẹ́ (1-10)

 • 25

  • Ìdájọ́ Jèhófà lórí àwọn orílẹ̀-èdè (1-38)

   • Àwọn orílẹ̀-èdè máa fi 70 ọdún sin Bábílónì (11)

   • Ife wáìnì ìbínú Ọlọ́run (15)

   • Àjálù láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè (32)

   • Àwọn tí Jèhófà pa (33)

 • 26

  • Wọ́n fi ikú halẹ̀ mọ́ Jeremáyà (1-15)

  • Wọ́n dá Jeremáyà sí (16-19)

   • Wọ́n fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àsọtẹ́lẹ̀ Míkà (18)

  • Wòlíì Úríjà (20-24)

 • 27

  • Àjàgà Bábílónì (1-11)

  • Ọlọ́run ní kí Sedekáyà fi ara rẹ̀ sábẹ́ Bábílónì (12-22)

 • 28

  • Jeremáyà àti Hananáyà tó jẹ́ wòlíì èké (1-17)

 • 29

  • Lẹ́tà tí Jeremáyà kọ sí àwọn tó wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì (1-23)

   • Ísírẹ́lì yóò pa dà lẹ́yìn 70 ọdún (10)

  • Iṣẹ́ tí wọ́n rán sí Ṣemáyà (24-32)

 • 30

  • Ìlérí ìpadàbọ̀sípò àti ìmúláradá (1-24)

 • 31

  • Àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì á tún pa dà máa gbé ilẹ̀ wọn (1-30)

   • Réṣẹ́lì ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ (15)

  • Májẹ̀mú tuntun (31-40)

 • 32

  • Jeremáyà ra ilẹ̀ (1-15)

  • Àdúrà Jeremáyà (16-25)

  • Ohun tí Jèhófà sọ (26-44)

 • 33

  • Ìlérí ìpadàbọ̀sípò (1-13)

  • Ààbò lábẹ́ “èéhù òdodo” (14-16)

  • Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Dáfídì àti àwọn àlùfáà dá (17-26)

   • Májẹ̀mú nípa ọ̀sán àti òru (20)

 • 34

  • Ọ̀rọ̀ ìdájọ́ sí Sedekáyà (1-7)

  • Wọ́n da májẹ̀mú tí wọ́n dá pé wọ́n á dá àwọn ẹrú sílẹ̀ (8-22)

 • 35

  • Àwọn ọmọ Rékábù jẹ́ onígbọràn tó ṣeé fara wé (1-19)

 • 36

  • Jeremáyà ń sọ ohun tí wọ́n ń kọ sínú àkájọ ìwé (1-7)

  • Bárúkù ka ọ̀rọ̀ inú àkájọ ìwé sókè (8-19)

  • Jèhóákímù dáná sun àkájọ ìwé náà (20-26)

  • A tún ọ̀rọ̀ náà kọ sínú àkájọ ìwé tuntun (27-32)

 • 37

  • Àwọn ará Kálídíà ṣígun lọ fúngbà díẹ̀ (1-10)

  • Wọ́n fi Jeremáyà sẹ́wọ̀n (11-16)

  • Sedekáyà pàdé Jeremáyà (17-21)

   • Wọ́n ń fún Jeremáyà ní búrẹ́dì (21)

 • 38

  • Wọ́n ju Jeremáyà sínú kòtò omi (1-6)

  • Ebedi-mélékì gba Jeremáyà sílẹ̀ (7-13)

  • Jeremáyà rọ Sedekáyà pé kó juwọ́ sílẹ̀ (14-28)

 • 39

  • Ìṣubú Jerúsálẹ́mù (1-10)

   • Sedekáyà fẹsẹ̀ fẹ, ṣùgbọ́n wọ́n gbá a mú (4-7)

  • Wọ́n máa dáàbò bo Jeremáyà (11-14)

  • Ọlọ́run máa dá ẹ̀mí Ebedi-mélékì sí (15-18)

 • 40

  • Nebusarádánì jẹ́ kí Jeremáyà lọ ní òmìnira (1-6)

  • A yan Gẹdaláyà ṣe olórí ilẹ̀ náà (7-12)

  • Wọ́n dìtẹ̀ Gẹdaláyà (13-16)

 • 41

  • Íṣímáẹ́lì pa Gẹdaláyà (1-10)

  • Íṣímáẹ́lì fẹsẹ̀ fẹ bó ṣe rí Jóhánánì (11-18)

 • 42

  • Àwọn èèyàn ní kí Jeremáyà gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà (1-6)

  • Jèhófà fèsì pé: “Ẹ má lọ sí Íjíbítì” (7-22)

 • 43

  • Àwọn èèyàn ṣàìgbọràn, wọ́n lọ sí Íjíbítì (1-7)

  • Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Jeremáyà ní Íjíbítì (8-13)

 • 44

  • Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àjálù fún àwọn Júù tó wà ní Íjíbítì (1-14)

  • Àwọn èèyàn kò gba ìkìlọ̀ Ọlọ́run (15-30)

   • Wọ́n jọ́sìn “Ọbabìnrin Ọ̀run” (17-19)

 • 45

  • Iṣẹ́ tí Jèhófà rán sí Bárúkù (1-5)

 • 46

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Íjíbítì (1-26)

   • Nebukadinésárì yóò ṣẹ́gun Íjíbítì (13, 26)

  • Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ísírẹ́lì (27, 28)

 • 47

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí àwọn Filísínì (1-7)

 • 48

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Móábù (1-47)

 • 49

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí àwọn ọmọ Ámónì (1-6)

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Édómù (7-22)

   • Édómù kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́ (17, 18)

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Damásíkù (23-27)

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Kédárì àti Hásórì (28-33)

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Élámù (34-39)

 • 50

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Bábílónì (1-46)

   • Ẹ sá kúrò nínú Bábílónì (8)

   • A ó mú Ísírẹ́lì pa dà wá (17-19)

   • A ó mú kí odò Bábílónì gbẹ (38)

   • Ẹnikẹ́ni kò ní gbé Bábílónì mọ́ (39, 40)

 • 51

  • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Bábílónì (1-64)

   • Bábílónì máa ṣubú lójijì sọ́wọ́ àwọn ará Mídíà (8-12)

   • Ó ju ìwé sínú odò Yúfírétì (59-64)

 • 52

  • Sedekáyà ṣọ̀tẹ̀ sí Bábílónì (1-3)

  • Nebukadinésárì dó ti Jerúsálẹ́mù (4-11)

  • Ìparun Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ (12-23)

  • Wọ́n kó àwọn èèyàn lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì (24-30)

  • Wọ́n dá Jèhóákínì sílẹ̀ lẹ́wọ̀n (31-34)