Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

Orí

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

 • 1

  • Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé (1, 2)

  • Àwọn ohun tí Ọlọ́run dá ní ọjọ́ kìíní sí ìkẹfà (3-31)

   • Ọjọ́ 1: ìmọ́lẹ̀; ọ̀sán àti òru (3-5)

   • Ọjọ́ 2: òfúrufú (6-8)

   • Ọjọ́ 3: ilẹ̀ àti ewéko (9-13)

   • Ọjọ́ 4: àwọn orísun ìmọ́lẹ̀ tó wà lọ́run (14-19)

   • Ọjọ́ 5: àwọn ẹja àtàwọn ẹyẹ (20-23)

   • Ọjọ́ 6: àwọn ẹran orí ilẹ̀ àti èèyàn (24-31)

 • 2

  • Ọlọ́run sinmi ní ọjọ́ keje (1-3)

  • Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé (4)

  • Ọkùnrin àti obìnrin nínú ọgbà Édẹ́nì (5-25)

   • Ọlọ́run fi erùpẹ̀ mọ ọkùnrin (7)

   • Wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ (15-17)

   • Ọlọ́run dá obìnrin (18-25)

 • 3

  • Bí èèyàn ṣe kọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀ (1-13)

   • Irọ́ àkọ́kọ́ (4, 5)

  • Jèhófà dá àwọn ọlọ̀tẹ̀ lẹ́jọ́ (14-24)

   • Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọmọ obìnrin náà (15)

   • Ọlọ́run lé Ádámù àti Éfà jáde ní Édẹ́nì (23, 24)

 • 4

  • Kéènì àti Ébẹ́lì (1-16)

  • Àtọmọdọ́mọ Kéènì (17-24)

  • Sẹ́ẹ̀tì àti Énọ́ṣì ọmọ rẹ̀ (25, 26)

 • 5

  • Látorí Ádámù dórí Nóà (1-32)

   • Ádámù bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin (4)

   • Énọ́kù bá Ọlọ́run rìn (21-24)

 • 6

  • Àwọn ọmọ Ọlọ́run fẹ́ ìyàwó ní ayé (1-3)

  • Wọ́n bí àwọn Néfílímù (4)

  • Ìwà búburú èèyàn ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́ (5-8)

  • Ọlọ́run ní kí Nóà kan áàkì (9-16)

  • Ọlọ́run kéde pé Ìkún Omi ń bọ̀ (17-22)

 • 7

  • Wọ́n ń wọ inú áàkì (1-10)

  • Ìkún Omi tó bo ayé (11-24)

 • 8

  • Omi ń fà (1-14)

   • Nóà rán àdàbà jáde (8-12)

  • Wọ́n ń kúrò nínú áàkì (15-19)

  • Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún ayé (20-22)

 • 9

  • Àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún aráyé (1-7)

   • Òfin nípa ẹ̀jẹ̀ (4-6)

  • Májẹ̀mú tí Ọlọ́run fi òṣùmàrè dá (8-17)

  • Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn àtọmọdọ́mọ Nóà (18-29)

 • 10

  • Àwọn orílẹ̀-èdè (1-32)

   • Àtọmọdọ́mọ Jáfẹ́tì (2-5)

   • Àtọmọdọ́mọ Hámù (6-20)

    • Nímírọ́dù ta ko Jèhófà (8-12)

   • Àtọmọdọ́mọ Ṣémù (21-31)

 • 11

  • Ilé Gogoro Bábélì (1-4)

  • Jèhófà da èdè rú (5-9)

  • Látorí Ṣémù dórí Ábúrámù (10-32)

   • Ìdílé Térà (27)

   • Ábúrámù kúrò ní Úrì (31)

 • 12

  • Ábúrámù kúrò ní Háránì lọ sí Kénáánì (1-9)

   • Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúrámù (7)

  • Ábúrámù àti Sáráì ní Íjíbítì (10-20)

 • 13

  • Ábúrámù pa dà sí Kénáánì (1-4)

  • Ábúrámù àti Lọ́ọ̀tì lọ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ (5-13)

  • Ọlọ́run tún ṣèlérí fún Ábúrámù (14-18)

 • 14

  • Ábúrámù gba Lọ́ọ̀tì sílẹ̀ (1-16)

  • Melikisédékì súre fún Ábúrámù (17-24)

 • 15

  • Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúrámù dá (1-21)

   • Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìjìyà fún 400 ọdún (13)

   • Ọlọ́run tún ṣèlérí fún Ábúrámù (18-21)

 • 16

  • Hágárì àti Íṣímáẹ́lì (1-16)

 • 17

  • Ábúráhámù yóò di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè (1-8)

   • Orúkọ Ábúrámù yí pa dà sí Ábúráhámù (5)

  • Májẹ̀mú nípa ìdádọ̀dọ́ (9-14)

  • Orúkọ Sáráì yí pa dà sí Sérà (15-17)

  • Ọlọ́run ṣèlérí pé yóò bí Ísákì (18-27)

 • 18

  • Áńgẹ́lì mẹ́ta wá sọ́dọ̀ Ábúráhámù (1-8)

  • Ó ṣèlérí pé Sérà yóò bímọ; Sérà rẹ́rìn-ín (9-15)

  • Ábúráhámù ń bẹ̀bẹ̀ torí Sódómù (16-33)

 • 19

  • Àwọn áńgẹ́lì wá sọ́dọ̀ Lọ́ọ̀tì (1-11)

  • Wọ́n rọ Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ pé kí wọ́n kúrò nílùú (12-22)

  • Sódómù àti Gòmórà pa run (23-29)

   • Ìyàwó Lọ́ọ̀tì di ọwọ̀n iyọ̀ (26)

  •  Lọ́ọ̀tì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ (30-38)

   • Ibi tí àwọn ọmọ Móábù àti Ámónì ti wá (37, 38)

 • 20

  • Ọlọ́run gba Sérà lọ́wọ́ Ábímélékì (1-18)

 • 21

  • Wọ́n bí Ísákì (1-7)

  • Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́ (8, 9)

  • Ó lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì lọ (10-21)

  • Ábúráhámù bá Ábímélékì dá májẹ̀mú (22-34)

 • 22

  • Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé kó fi Ísákì rúbọ (1-19)

   • Àwọn èèyàn yóò rí ìbùkún gbà torí àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù (15-18)

  • Ìdílé Rèbékà (20-24)

 • 23

  • Ikú Sérà àti ibi ìsìnkú (1-20)

 • 24

  • Wọ́n bá Ísákì wá ìyàwó (1-58)

  • Rèbékà lọ bá Ísákì (59-67)

 • 25

  • Ábúráhámù fẹ́ ìyàwó míì (1-6)

  • Ábúráhámù kú (7-11)

  • Àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì (12-18)

  • Wọ́n bí Jékọ́bù àti Ísọ̀ (19-26)

  • Ísọ̀ ta ogún ìbí rẹ̀ (27-34)

 • 26

  • Ísákì àti Rèbékà ní Gérárì (1-11)

   • Ọlọ́run fìdí ìlérí tó ṣe fún Ísákì múlẹ̀ (3-5)

  • Wọ́n ń jà torí kànga (12-25)

  • Ísákì àti Ábímélékì dá májẹ̀mú (26-33)

  • Àwọn ọmọ Hétì méjì tí Ísọ̀ fẹ́ (34, 35)

 • 27

  • Jékọ́bù gba ìbùkún lọ́dọ̀ Ísákì (1-29)

  • Ísọ̀ fẹ́ gba ìbùkún àmọ́ kò ronú pìwà dà (30-40)

  • Ísọ̀ di Jékọ́bù sínú (41-46)

 • 28

  • Ísákì ní kí Jékọ́bù lọ sí Padani-árámù (1-9)

  • Àlá tí Jékọ́bù lá ní Bẹ́tẹ́lì (10-22)

   • Ọlọ́run tún ìlérí rẹ̀ sọ fún Jékọ́bù (13-15)

 • 29

  • Jékọ́bù pàdé Réṣẹ́lì (1-14)

  • Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ Réṣẹ́lì (15-20)

  • Jékọ́bù fẹ́ Líà àti Réṣẹ́lì (21-29)

  • Àwọn ọmọ mẹ́rin tí Líà bí fún Jékọ́bù: Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì àti Júdà (30-35)

 • 30

  • Bílíhà bí Dánì àti Náfútálì (1-8)

  • Sílípà bí Gádì àti Áṣérì (9-13)

  • Líà bí Ísákà àti Sébúlúnì (14-21)

  • Réṣẹ́lì bí Jósẹ́fù (22-24)

  • Agbo ẹran Jékọ́bù ń pọ̀ sí i (25-43)

 • 31

  • Jékọ́bù yọ́ lọ sí Kénáánì (1-18)

  • Lábánì lé Jékọ́bù bá (19-35)

  • Jékọ́bù àti Lábánì dá májẹ̀mú (36-55)

 • 32

  • Àwọn áńgẹ́lì pàdé Jékọ́bù (1, 2)

  • Jékọ́bù múra láti pàdé Ísọ̀ (3-23)

  • Jékọ́bù bá áńgẹ́lì kan jìjàkadì (24-32)

   • Orúkọ Jékọ́bù yí pa dà di Ísírẹ́lì (28)

 • 33

  • Jékọ́bù lọ pàdé Ísọ̀ (1-16)

  • Jékọ́bù lọ sí Ṣékémù (17-20)

 • 34

  • Ṣékémù fipá bá Dínà lò pọ̀ (1-12)

  • Àwọn ọmọ Jékọ́bù ṣẹ̀tàn (13-31)

 • 35

  • Jékọ́bù mú àwọn ọlọ́run àjèjì kúrò (1-4)

  • Jékọ́bù pa dà sí Bẹ́tẹ́lì (5-15)

  • Réṣẹ́lì bí Bẹ́ńjámínì; Réṣẹ́lì kú (16-20)

  • Àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì méjìlá (21-26)

  • Ísákì kú (27-29)

 • 36

  • Àtọmọdọ́mọ Ísọ̀ (1-30)

  • Àwọn ọba àti àwọn séríkí Édómù (31-43)

 • 37

  • Àwọn àlá Jósẹ́fù (1-11)

  • Jósẹ́fù àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ òjòwú (12-24)

  • Wọ́n ta Jósẹ́fù sí oko ẹrú (25-36)

 • 38

  • Júdà àti Támárì (1-30)

 • 39

  • Jósẹ́fù ní ilé Pọ́tífárì (1-6)

  • Jósẹ́fù ò gbà fún ìyàwó Pọ́tífárì (7-20)

  • Jósẹ́fù ṣẹ̀wọ̀n (21-23)

 • 40

  • Jósẹ́fù túmọ̀ àlá àwọn ẹlẹ́wọ̀n (1-19)

   • “Ọlọ́run ló ni ìtúmọ̀” (8)

  • Àsè ọjọ́ ìbí Fáráò (20-23)

 • 41

  • Jósẹ́fù túmọ̀ àlá Fáráò (1-36)

  • Fáráò gbé Jósẹ́fù ga (37-46a)

  • Jósẹ́fù ń bójú tó ọ̀rọ̀ oúnjẹ (46b-57)

 • 42

  • Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì (1-4)

  • Jósẹ́fù rí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó sì dán wọn wò (5-25)

  • Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pa dà sọ́dọ̀ Jékọ́bù nílé (26-38)

 • 43

  • Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù pa dà sí Íjíbítì; pẹ̀lú Bẹ́ńjámínì (1-14)

  • Jósẹ́fù tún rí àwọn arákùnrin rẹ̀ (15-23)

  • Jósẹ́fù jẹun pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ (24-34)

 • 44

  • Wọ́n rí ife fàdákà Jósẹ́fù nínú àpò Bẹ́ńjámínì (1-17)

  • Júdà bá Bẹ́ńjámínì bẹ̀bẹ̀ (18-34)

 •  45

  • Jósẹ́fù jẹ́ kí wọ́n mọ òun (1-15)

  • Àwọn arákùnrin Jósẹ́fù pa dà lọ mú Jékọ́bù wá (16-28)

 • 46

  • Jékọ́bù àti agbo ilé rẹ̀ kó lọ sí Íjíbítì (1-7)

  • Orúkọ àwọn tó ń kó lọ sí Íjíbítì (8-27)

  • Jósẹ́fù lọ pàdé Jékọ́bù ní Góṣénì (28-34)

 • 47

  • Jékọ́bù lọ sọ́dọ̀ Fáráò (1-12)

  • Jósẹ́fù fi ọgbọ́n darí nǹkan (13-26)

  • Ísírẹ́lì ń gbé ní Góṣénì (27-31)

 • 48

  • Jékọ́bù súre fún àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù méjèèjì (1-12)

  • Ìbùkún Éfúrémù ló pọ̀ jù (13-22)

 • 49

  • Jékọ́bù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú (1-28)

   • Ṣílò yóò wá láti Júdà (10)

  • Ìtọ́ni Jékọ́bù nípa ìsìnkú rẹ̀ (29-32)

  • Jékọ́bù kú (33)

 • 50

  • Jósẹ́fù sin Jékọ́bù sí Kénáánì (1-14)

  • Jósẹ́fù fi dá àwọn arákùnrin rẹ̀ lójú pé òun ti dárí jì wọ́n (15-21)

  • Jósẹ́fù darúgbó, ó sì kú (22-26)

   • Àṣẹ tí Jósẹ́fù pa nípa àwọn egungun rẹ̀ (25)