Sekaráyà 9:1-17
9 Ìkéde:
“Jèhófà bá ilẹ̀ Hádírákì wí,Damásíkù gangan ni ọ̀rọ̀ náà kàn,*+Torí ojú Jèhófà wà lára aráyé+Àti lára gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
2 Ọ̀rọ̀ náà tún kan Hámátì+ tí wọ́n jọ pààlàÀti Tírè+ pẹ̀lú Sídónì,+ torí wọ́n gbọ́n féfé.+
3 Tírè kọ́ odi ààbò* fún ara rẹ̀.
Ó to fàdákà jọ pelemọ bí iyẹ̀pẹ̀Àti wúrà bí iyẹ̀pẹ̀ ojú ọ̀nà.+
4 Wò ó! Jèhófà máa gba àwọn ohun ìní rẹ̀,Yóò sì run àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sínú òkun;*+Iná yóò sì jẹ ẹ́ run.+
5 Áṣíkẹ́lónì á rí i, ẹ̀rù á sì bà á;Gásà yóò jẹ̀rora,Bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹ́kírónì, torí pé ìrètí rẹ̀ ti di ìtìjú.
Ọba kan yóò ṣègbé ní Gásà,Ẹnì kankan kò sì ní gbé ní Áṣíkẹ́lónì.+
6 Ọmọ àjèjì ni yóò gbé ní Áṣídódì,Màá sì fòpin sí ìgbéraga ará Filísínì.+
7 Èmi yóò mú àwọn ohun tí ẹ̀jẹ̀ ti yí kúrò ní ẹnu rẹ̀Àti àwọn ohun ìríra kúrò láàárín eyín rẹ̀,Àwọn tó ṣẹ́ kù níbẹ̀ yóò sì di ti Ọlọ́run wa;Òun yóò dà bí séríkí* ní Júdà,+Ẹ́kírónì yóò sì dà bí àwọn ará Jébúsì.+
8 Èmi yóò pàgọ́ bí ẹ̀ṣọ́* fún ilé mi,+Kí ẹnì kankan má bàa gba ibẹ̀ kọjá tàbí pa dà wá;Akóniṣiṣẹ́* kankan kò ní gba ibẹ̀ kọjá mọ́,+Torí mo ti fi ojú mi rí i* báyìí.
9 Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.
Kígbe ìṣẹ́gun, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù.
Wò ó! Ọba rẹ ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ.+
Olódodo ni, ó sì ń mú ìgbàlà bọ̀,*Ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀,+ ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,Àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* ọmọ abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+
10 Èmi yóò mú kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí wọ́n fi ń jagun kúrò ní ÉfúrémùÀti ẹṣin kúrò ní Jerúsálẹ́mù.
Ọfà tí wọ́n fi ń jagun kò ní sí mọ́.
Òun yóò sì kéde àlàáfíà fún àwọn orílẹ̀-èdè;+Yóò jọba láti òkun dé òkunÀti láti Odò* dé àwọn ìkángun ayé.+
11 Ní ti ìwọ obìnrin, nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú rẹ,Èmi yóò rán àwọn ẹlẹ́wọ̀n rẹ jáde kúrò nínú kòtò tí kò lómi.+
12 Ẹ pa dà síbi ààbò, ẹ̀yin ẹlẹ́wọ̀n tó ní ìrètí.+
Mò ń sọ fún ọ lónìí pé,‘Ìwọ obìnrin, màá san án pa dà fún ọ ní ìlọ́po méjì.+
13 Torí èmi yóò fa* Júdà bí ọrun mi.
Màá fi Éfúrémù sínú ọrun* náà,Màá sì jí àwọn ọmọ rẹ, ìwọ Síónì,Láti dojú kọ àwọn ọmọ rẹ, ìwọ ilẹ̀ Gíríìsì,Màá sì ṣe ọ́ bí idà jagunjagun.’
14 Ó máa hàn pé Jèhófà wà pẹ̀lú wọn,Ọfà rẹ̀ á sì jáde lọ bíi mànàmáná.
Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò fun ìwo,+Yóò sì gbéra pẹ̀lú ìjì líle ti gúúsù.
15 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun yóò gbèjà wọn,Wọn yóò jẹ òkúta kànnàkànnà run, wọn yóò sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.+
Wọ́n á mu, wọ́n á sì pariwo bíi pé wọ́n mu wáìnì;Wọn yóò kún bí abọ́ tí wọ́n fi ń rúbọ,Bí àwọn igun pẹpẹ.+
16 Jèhófà Ọlọ́run wọn yóò gbà wọ́n là ní ọjọ́ yẹn,Àwọn èèyàn rẹ̀, bí agbo àgùntàn;+Torí wọn yóò dà bí òkúta iyebíye tó wà lára adé* tó ń dán yinrin lórí ilẹ̀ rẹ̀.+
17 Oore rẹ̀ mà pọ̀ o,+Ó mà lẹ́wà gan-an o!
Ọkà yóò mú kí àwọn géńdé ọkùnrin lágbára,Wáìnì tuntun yóò sì fún àwọn wúńdíá lókun.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “ni ibi ìsinmi rẹ̀.”
^ Tàbí “ilé ààbò.”
^ Tàbí kó jẹ́, “lórí òkun.”
^ Séríkí jẹ́ olóyè láàárín ẹ̀yà kan.
^ Ó ṣe kedere pé, ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ ló ń sọ.
^ Tàbí “aninilára.”
^ Tàbí “ọmọ ogun ẹ̀yìn odi.”
^ Tàbí “ó sì ń ṣẹ́gun; ó sì gbani là.”
^ Tàbí “akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”
^ Ìyẹn, odò Yúfírétì.
^ Ní Héb., “tẹ.”
^ Ìyẹn, bí ọfà.
^ Tàbí “dáyádémà.”

