Sekaráyà 2:1-13

  • Ìran 3: Ọkùnrin kan mú okùn ìdíwọ̀n dání (1-13)

    • Wọ́n máa wọn Jerúsálẹ́mù (2)

    • Jèhófà, ‘di ògiri iná yí i ká’ (5)

    • Bí wọ́n ṣe fọwọ́ kan ẹyinjú Ọlọ́run (8)

    • Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò fara mọ́ Jèhófà (11)

2  Mo wòkè, mo sì rí ọkùnrin kan tó mú okùn ìdíwọ̀n+ dání. 2  Torí náà, mo bi í pé: “Ibo lò ń lọ?” Ó fèsì pé: “Mo fẹ́ lọ wọn Jerúsálẹ́mù kí n lè mọ bó ṣe fẹ̀ tó àti bó ṣe gùn tó.”+ 3  Wò ó! áńgẹ́lì tó ń bá mi sọ̀rọ̀ jáde lọ, áńgẹ́lì míì sì wá pàdé rẹ̀. 4  Ó wá sọ fún un pé: “Sáré lọ síbẹ̀ yẹn, kí o sì sọ fún ọkùnrin yẹn pé, ‘“Wọn yóò gbé inú Jerúsálẹ́mù+ bí ìgbèríko gbalasa,* nítorí gbogbo èèyàn àti ẹran ọ̀sìn tó máa wà nínú rẹ̀.”+ 5  Jèhófà kéde pé, “Èmi yóò di ògiri iná fún un yí ká,+ màá sì mú kí ògo mi wà láàárín rẹ̀.”’”+ 6  Jèhófà kéde pé, “Ẹ wá! Ẹ wá! Ẹ sá kúrò ní ilẹ̀ àríwá.”+ “Torí mo ti fọ́n yín káàkiri,”*+ ni Jèhófà wí. 7  “Wá, Síónì! Sá àsálà, ìwọ tí ń gbé pẹ̀lú ọmọbìnrin Bábílónì.+ 8  Torí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, lẹ́yìn tí a ti yìn ín lógo, ó rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tó ń kó ẹrù yín,+ pé; ‘Ẹni tó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú* mi.+ 9  Wọ́n á rí ìbínú mi, àwọn ìránṣẹ́ wọn yóò sì kó ẹrù wọn.’+ Ó sì dájú pé ẹ máa mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló rán mi. 10  “Kígbe ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Síónì;+ torí mò ń bọ̀,+ èmi yóò sì máa gbé láàárín rẹ,”+ ni Jèhófà wí. 11  “Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò fara mọ́ Jèhófà ní ọjọ́ náà,+ wọ́n á sì di èèyàn mi; èmi yóò sì máa gbé láàárín yín.” Ẹ ó sì mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló rán mi sí yín. 12  Jèhófà yóò gba Júdà bí ìpín rẹ̀ lórí ilẹ̀ mímọ́, yóò sì tún Jerúsálẹ́mù yàn.+ 13  Gbogbo aráyé,* ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà torí ó ń gbé ìgbésẹ̀ láti ibi mímọ́ tó ń gbé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Ìyẹn, ìlú tí kò ní odi.
^ Ní Héb., “sí afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.”
^ Tàbí “ojú.”
^ Tàbí “ẹran ara.”