Sekaráyà 14:1-21
14 “Wò ó! Ọjọ́ náà ń bọ̀. Ti Jèhófà ni ọjọ́ náà, àárín yín ni wọn yóò ti pín ẹrù yín* tí wọ́n kó ní ọjọ́ náà.
2 Màá kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ láti gbógun ti Jerúsálẹ́mù; wọ́n á gba ìlú náà, wọ́n á kó ẹrù nínú àwọn ilé, wọ́n á sì fipá bá àwọn obìnrin lò pọ̀. Ìdajì ìlú náà á sì lọ sí ìgbèkùn, àmọ́ wọn ò ní kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn náà kúrò ní ìlú náà.
3 “Jèhófà yóò jáde lọ gbéjà ko àwọn orílẹ̀-èdè+ yẹn bí ìgbà tó ń jà ní ọjọ́ ogun.+
4 Ní ọjọ́ yẹn, ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò dúró sórí Òkè Ólífì,+ tó dojú kọ Jerúsálẹ́mù ní ìlà oòrùn; Òkè Ólífì yóò là sí méjì láti ìlà oòrùn* dé ìwọ̀ oòrùn,* àfonífojì ńlá kan yóò sì wà láàárín rẹ̀; ìdajì òkè náà yóò sún sí àríwá àti ìdajì sí gúúsù.
5 Ẹ máa sá lọ sí àfonífojì àárín àwọn òkè mi; torí àfonífojì àárín àwọn òkè náà yóò dé Ásélì lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún. Ẹ máa sá lọ, bí ẹ ṣe sá lọ torí ìmìtìtì ilẹ̀ láyé ìgbà Ùsáyà ọba Júdà.+ Jèhófà Ọlọ́run mi yóò wá, gbogbo àwọn ẹni mímọ́ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+
6 “Ní ọjọ́ yẹn, kò ní sí ìmọ́lẹ̀ tó tàn yòò;+ àwọn nǹkan yóò dì.*
7 Yóò sì di ọjọ́ kan tí a mọ̀ sí ti Jèhófà.+ Kò ní jẹ́ ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni kò ní jẹ́ òru; ìmọ́lẹ̀ yóò sì wà ní ìrọ̀lẹ́.
8 Ní ọjọ́ yẹn, omi ìyè+ yóò ṣàn jáde láti Jerúsálẹ́mù,+ ìdajì rẹ̀ sí ọ̀nà òkun ìlà oòrùn*+ àti ìdajì rẹ̀ sí ọ̀nà òkun ìwọ̀ oòrùn.*+ Yóò ṣẹlẹ̀ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ní ìgbà òtútù.
9 Jèhófà yóò sì jẹ́ Ọba lórí gbogbo ayé.+ Jèhófà yóò jẹ́ ọ̀kan ní ọjọ́ yẹn,+ orúkọ rẹ̀ yóò sì jẹ́ ọ̀kan.+
10 “Gbogbo ilẹ̀ náà láti Gébà+ dé Rímónì+ ní gúúsù Jerúsálẹ́mù yóò dà bí Árábà;+ yóò dìde, yóò sì máa gbé àyè rẹ̀,+ láti Ẹnubodè Bẹ́ńjámínì+ títí lọ dé ibi Ẹnubodè Àkọ́kọ́, títí lọ dé Ẹnubodè Igun àti láti Ilé Gogoro Hánánélì+ títí lọ dé àwọn ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì* tó jẹ́ ti ọba.
11 Àwọn èèyàn yóò gbé inú rẹ̀; kò tún ní sí ìparun tí ègún fà mọ́,+ wọn yóò sì máa gbé Jerúsálẹ́mù ní àlàáfíà.+
12 “Èyí ni àjàkálẹ̀ àrùn tí Jèhófà yóò fi kọ lu gbogbo èèyàn tó bá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù:+ Ẹran ara wọn yóò jẹrà lórí ìdúró, ojú wọn yóò jẹrà ní agbárí wọn, ahọ́n wọn yóò sì jẹrà ní ẹnu wọn.
13 “Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà yóò da àárín wọn rú; kálukú wọn yóò gbá ọwọ́ ẹnì kejì rẹ̀ mú, wọn yóò sì gbéjà ko ara wọn.*+
14 Júdà pẹ̀lú yóò jagun ní Jerúsálẹ́mù; ọrọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ni wọ́n á sì kó jọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà àti fàdákà àti aṣọ.+
15 “Irú àjàkálẹ̀ àrùn yẹn yóò tún kọ lu àwọn ẹṣin, ìbaaka, ràkúnmí, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti gbogbo ẹran ọ̀sìn tó wà nínú àwọn àgọ́ yẹn.
16 “Gbogbo ẹni tó ṣẹ́ kù nínú gbogbo orílẹ̀-èdè tó wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù yóò máa lọ láti ọdún dé ọdún+ kí wọ́n lè tẹrí ba fún* Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ Ọba,+ kí wọ́n sì lè ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà.+
17 Àmọ́ tí ẹnì kankan nínú àwọn ìdílé tó wà ní ayé kò bá lọ sí Jerúsálẹ́mù láti tẹrí ba fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ Ọba, òjò kò ní rọ̀ sórí wọn.+
18 Tí ìdílé àwọn ará Íjíbítì kò bá wá, tí wọn ò sì wọlé wá, òjò kò ní rọ̀ sórí wọn. Dípò ìyẹn, àjàkálẹ̀ àrùn tí Jèhófà fi kọ lu àwọn orílẹ̀-èdè tí kò wá ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà ni yóò kọ lù wọ́n.
19 Èyí ni yóò jẹ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ Íjíbítì àti ìyà ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò wá ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà.
20 “Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò kọ ọ̀rọ̀ náà, ‘Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà!’+ sára àwọn agogo tí wọ́n so mọ́ àwọn ẹṣin. Àwọn ìkòkò oúnjẹ*+ inú ilé Jèhófà yóò sì dà bí àwọn abọ́+ níwájú pẹpẹ.
21 Gbogbo ìkòkò oúnjẹ* ní Jerúsálẹ́mù àti Júdà yóò di mímọ́, yóò sì jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, gbogbo àwọn tó ń rúbọ yóò wọlé wá, wọn yóò sì lò lára rẹ̀ láti fi se nǹkan. Ní ọjọ́ yẹn, kò ní sí ọmọ Kénáánì* kankan mọ́ nínú ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, ìlú tó wà nínú ẹsẹ 2.
^ Tàbí “yíyọ oòrùn.”
^ Ní Héb., “òkun.”
^ Tàbí “dúró gbagidi,” bíi pé òtútù mú kó gan.
^ Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.
^ Ìyẹn, Òkun Òkú.
^ Tàbí “dé ẹkù ìfúntí.”
^ Tàbí “ọwọ́ rẹ̀ yóò sì gbéjà ko ọwọ́ ẹnì kejì rẹ̀.”
^ Tàbí “jọ́sìn.”
^ Tàbí “ìkòkò ìsebẹ̀ ẹlẹ́nu fífẹ̀.”
^ Tàbí “ìkòkò ìsebẹ̀ ẹlẹ́nu fífẹ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́, “oníṣòwò.”